Ìyá arúgbó ẹni ọdún 78 wọ gbaga fẹ́sùn ìdigunjalè

Iya arugbo ẹni ọdun mejidinlọgọrin kan, to ti lọ si ẹwọn ni igba meji ọtọtọ fun iwa idigunjale, tun ti ri ẹwọn he fún ẹsun idigunjale miran bayii nilu Missouri, lorilẹede Amẹrika.

Awọn ọlọpaa ṣalaye pe, iya arugbo naa ti orukọ n jẹ Bonnie Gooch, wọ banki Goppert Financial Bank, ti o si fun oṣiṣẹ banki naa kan ni iwe pelebe kan ninu eyi to ti n beere fun ẹgbẹlẹgbẹ owo.

Bakan naa ni wọn tun ṣalaye pe o tun fi iwe pelebe miran silẹ nigba to n kuro ni banki naa ninu eyito kọ ọ si pe:

“Mo dupẹ, ma binu, mi o mọọmọ dẹru ba ọ” ki o to gbe owo naa lọ pẹlu ọkọ to gbe wa jale naa.

"Booch wọ iboju, awo oju dudu pelu ibọwọ wọ banki lati jale"

Iya arugbo Gooch ti n fi aṣọ penpe roko ọba bayii pẹlu owo itanran ẹgbẹrun marundinlọgbọn dollar ($25,000) lori rẹ.

Gẹgẹ bi awọn akọsilẹ to wa ni iwaju ile ẹjọ ṣe sọ, Booch wọ iboju, awo oju dudu pelu ibọwọ wọ banki naa ni Ọjọru to kọja nibi to ti fi iwe pelebe to kọ “ mo nilo owo ẹgbẹrun mẹtala le oṣiṣẹ kanta banki naa lọwọ”

Iya arugbo adigunjale naa n run kula fun ogogoro, ti owo si fọn kalẹ kaakiri nigba ti ọlọpaa de

Awọn ohun elo ayaworan feto aabo fi Gooch han nibi to ti n gba ọwọ mọ kanta kikankikan pe ki wọn da oun lohun, ki o to fi banki naa silẹ ninu ọkọ Buick enclave rẹ.

Gẹgẹ bi awọn olupẹjọ ṣe sọ, awọn ọlọpaa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Pleasant Hill ni Missouri sare kankan de banki naa lẹyin ti wọn gba ipe pajawiri pe “ iṣẹlẹ idigunjale n lọ lọwọ “ nibẹ.

Wọn ni bii deede agogo mẹta ọsan kọja ogun iṣẹju ni awọn ọlọpaa de, ti wọn si ri iya arugbo naa ninu ọkọ rẹ to si n run kula fun ogogoro, ti awọn owo si tu kaakiri ilẹ.

Wọn fi panpẹ ofin mu iya arugbo Gooch, wọn si fi ẹsun ole jija tabi gbigbiyanju lati ja ile ifowopamọ si lole kan an.

“Nigba ti awọn ọlọpaa kọkọ dé ọdọ rẹ, iyalẹnu kọkọ ṣe wọn nigba ti wọn rii pe iya arugbo ni afurasi to bọ silẹ ninu ọkọ naa.”

Oga ọlọpaa nileeṣẹ ọlọpaa Pleasant Hill, Tommy Wright ṣalaye fun iwe iroyin Kansas City Star pe, “ A kọkọ n woye pe ṣe ẹni gan an to daran yii la mu ni abi ẹlomiran.”

Igba akọkọ kọ niyi ti iya arugbo Gooch yoo maa ko si gbaga ofin

Amọṣa igba akọkọ kọ niyi ti iya arugbo Gooch yoo maa ko si gbaga ofin.

Iya arugbo Gooch ti fi aṣọ penpe roko ọba nigba meji ọtọtọ saaju eyi.

Akọkọ waye lọdun 1977 fun ẹsun idigunjale ni Carlifornia ki o to tun wa lu gbaga ofin lọdun 2020.

Nibi to ti fun oṣiṣẹ ori kanta banki kan ni kaadi ikini ku ọjọ ibi, eyi ti wọn kọ “idigunjale niyi o” si ori rẹ.

Losu kọkanla ọdun 2021 ni o ṣẹṣẹ pari eto idarijin ti wọn n pe ni ‘probation' rẹ ki o to tun tẹri si eyi.

Ọga ọlọpaa Wright ni ko si akọsilẹ pe arun kankan n ṣe iya arugbo Gooch.

Amọ ṣa nitori ọjọ ori rẹ, ileeṣẹ ọlọpaa n gbiyan lati woye boya ipenija ilera kankan le wa to fa iṣẹlẹ yii.