You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ààrẹ Cote D‘Ivoire, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin, wọlé fún sáà kẹrin lẹ́yìn tó wọn fòfin de alátàkò rẹ̀ méjì
Aarẹ ilẹ Cote D‘Ivoire, Alassane Ouattara tun ti wọle ibo aarẹ fun igba kẹrin.
Aseyọri yii waye lẹyin ikede esi ibo to waye lọjọ Satide to kọja.
Quattara si wọle ibo aarẹ naa tori bi wọn se fofin de alatako rẹ meji pe wọn ko gbọdọ dije fun ipo aarẹ.
Eyi si jẹyọ ninu esi ibo ti wọn kede naa.
Ajọ eleto idibo ni orilẹede naa kede lọjọ Aje pe Ouattara, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin, bori ibo naa pẹlu ibo 89.8%.
Gbajumọ olokoowo kan, Jeal-Louis Billon, si lo se ipo keji pẹlu ibo 3.09% pere.
Aseyọri nla yii si lo jẹ iyalẹnu nla nitori aarẹ ana nilẹ naa, Laurent Gbagbo ati Credit Suisse ex-CEO Tidjane Thiam ti wọn ni wọn ko gbọdọ kopa ninu eto idibo naa, ti rọ awọn alatako wọn lati mase kopa ninu eto idibo ọhun.
Ida aadọta ninu ọgọrun awọn oludibo lo kopa ninu eto idibo naa gẹgẹ bi ajọ eleto idibo se salaye.
Iyawo Gbagbo tẹlẹ, Simone Gbagbo, ti wọn gba laaye lati dije ninu idibo naa , ni ibo 2.42%.
Esi ibo ti wọn kede yii jẹ asekagba abajade esi ibo ti ajọ eleto idibo kede esi ibo naa lẹyin agbeyẹwo awọn ẹsun ibo.
Ni ọjọ Isinmi, ẹgbẹ oselu alatako meji to jẹ ti Gbagbo and Thiam kẹyin si abajade esi ibo naa.
Wọn si se apejuwe esi ibo naa bii iditẹ gbajọba, ti wọn si fikun pe awọn ko ni ri aarẹ Ouattara bii asaaju ti ilu dibo yan.
Ọdun 2011 ni Ouattara kọkọ de ipo aarẹ lẹyin ti wọn gbe Laurent Gbagbo si ahamọ tori bo se yari lati gba ijakulẹ ninu eto idibo ọdun 2010.
Saa meji pere ni ofin kọkọ sọ pe Ouattara yoo lo lori aleefa bii aarẹ, amọ lọdun 2016, wọn se atunse si ofin idibo.
Igbesẹ yii si lo fi aaye gba a lati tun wọle sipo aarẹ lọdun 2020, idibo naa si ni ọpọ awọn oloselu alatako kẹyin si.