You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìwọ́de gbóná ní Cameroon, èèyàn mẹ́rin kú saájú ìkéde èsì ìbò ààrẹ
- Author, Paul Njie
- Role, BBC Africa
- Reporting from, Garoua, Cameroon
- Author, Seher Asaf
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
O kere ju eniyan mẹrin ni o padanu ẹmi lasiko ifẹhonuhan ni olu-ilu ọrọ-aje Cameroon, Douala, awọn alaṣẹ sọ, ṣaaju ikede abajade eto idibo aarẹ orilẹede naa.
Gomina agbegbe, Samuel Dieudonné Diboua, sọ pe awọn ileeṣẹ ọlọpaa ti wa labẹ ikọlu ti awọn ẹsọ alaabo si ni lati daabobo ara wọn.
Awọn alatilẹyin oludije aarẹ lati ẹgbẹ oṣelu alatako, Issa Tchiroma Bakary, tako ofin to de awọn ehonu ni ọpọlọpọ gbe kalẹ.
Tchiroma Bakary ti n tẹnumọ pe oun lo ṣẹgun eto idibo aarẹ ti o waye ni ọjọ kejila oṣu Kẹwaa ọdun 2025, lati gba agbara lọwọ aarẹ Paul Biya, to ti w ani ipo olori fun ọdun mẹtalelogoji. Ẹgbẹ oṣelu CPDM wogile erongba yii.
Diboua bu ẹnu atẹlu iwọde naa, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii iwa panle to le da alaafia ili laamu ati aabo orilẹ-ede.
"O se ni laanu pe eeyan mẹrin padanu ẹmi wọn," o sọ, o fikun pe ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ aabo tun farapa yanayana.
"A ti ṣii awọn iwadii, ki imọlẹ le tan lori awọn iṣẹlẹ wọnyi," o fi kun, lakoko ti o n halẹ lati gbe igbese lori awọn oludasilẹ iwọde.
Ni ilu Tchiroma Bakary ti Garoua, ilu kan ni ariwa ti orilẹ-ede naa, awọn ọlọpaa ta gaasi tajutaju ati ọpa omi si awọn alatilẹyin rẹ.
Awọn olufẹnhonuhan n tako ohun ti wọn sọ pe o jẹ eto ti ẹgbẹ ti n ṣe ijọba, Cameroon People's Democratic Movement (CPDM), lati "ji iṣẹgun naa" lati ọdọ oludari ẹgbẹ alatako naa.
Ifẹhonuhan yii waye lẹyin ti Tchiroma Bakary ke si awọn alatilẹyin rẹ ni orilẹ-ede naa ati awọn ara ilu okeere lati rin irin alaafia lati "gba ominira Cameroon".
Awọn alaṣẹ ti fi ofin de apejọ kankan titi di ọjọ Aje, nigba ti igbimọ t'olofin ti Ilu Kamẹrika ti ṣeto lati kede abajade eto idibo.
Ni Garoua, ifẹhonuhan bẹrẹ pẹlu alaafia ṣugbọn o yipada nigbati awọn ẹṣọ aabo ju tajutaju si aarin araalu, ti ero si bẹrẹ si ni ma pọsi lati ṣe atilẹyin fun Tchiroma Bakary.
"A ko wa nibi fun rudurudu. A n beere fun otitọ eto idibo naa, ".
A rii alatako kan ti o gbe asia kan ti n rọ Aarẹ Amẹrika, Donald Trump lati ṣe iranlọwọ fun wọn.
"A wa nibi lati beere iṣẹgun wa. A n ṣe irin-ajo alaafia, eyiti o jẹ ẹtọ ti araalu fun gbogbo ọmọ Cameroon - fun gbogbo eniyan, " olufẹhonuhan miiran sọ.
Awọn alatilẹyin tun bọ si awọn opopona ni guusu iwọ-oorun ilu Douala. "A fẹ Tchiroma, a fẹ Tchiroma," awọn olufẹhonuhan kọrin, ileeṣẹ iroyin Reuters jabọ
Tchiroma Bakary sọ tẹlẹ fun BBC pe oun ko ni gba ibo jiji.
O sọ pe ẹgbẹ rẹ ti ṣe akojọpọ aworan gbogbogbo ti o da lori awọn abajade lati awọn ibudo idibo kọọkan.
Ninu fidio kan to gbe si lori ayelujara, Tchiroma Bakary sọ pe o ti ṣẹgun idibo pẹlu iwọn 55% ti ibo,
Ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin [76] to jẹ minisita ìjọba tẹlẹ ri ja ni ipo pẹlu Biya, ẹni ọdún mejìlelọgọrun-un [92], to n wa ipo lẹyin ọdun mẹtalelogoji ni ijọba.