Mo bá Bàbá Ogunde ṣiṣẹ́ tó bíi ọdún márùn-un, owó ló díjà sílẹ̀ tí mo fi kúrò - Papalolo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọkan lara awọn agba oṣere aye ọjọun ni Alagba Ayo Ogunsina, ṣugbọn orukọ ti awọn eeyan mọ ọn si ni Papalolo.

Alawada ni Papalolo ati awọn meji yooku ti wọn jọ jẹ gbajumọ oṣere nigba naa, iyẹn Ọgbẹni Kayode Olaiya (Aderupoko) ati ẹnikẹta wọn to ti ku , Oloogbe Taju Gbadamosi ti wọn n pe ni Jacob.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Papalolo ṣe pẹ̀lú àgbà Akọroyin kan, Laolu Olatunbosun lójú òpó YouTube rẹ lo ti ṣalaye irinajo rẹ ko too di ẹni to n ṣe ere ori itage ati awada.

Ọmọ bibi ilu Ilesa naa si tun sọ pe awọn ọdọ oṣere asiko yii ko gba pe awọn ti awọn jẹ agbalagba mọ iṣẹ naa ṣe bii tiwọn mọ.

"Awọn ti asiko yii ri i pe a ti dagba, awa ko dẹ ni kakus (caucus) bii ti wọn, nitori naa, a ko mọ ere ṣe bii ti wọn mọ.

" Nigba ti a bẹrẹ ni tiwa, ifẹ la fi bẹrẹ, ka ba ara wa ṣe. Ṣugbọn awọn ti asiko yii ko gba pe a ṣi le ṣiṣẹ mọ.

"Bi okete naa ba si ti dagba, o maa n jokoo sile ni.

Ki i ṣe ọmu ọmọ rẹ ni yoo maa mu mọ bayii.''

Bẹẹ ni agba oṣẹre naa wi.

Mo bá Bàbá Ogunde ṣiṣẹ́ tó bíi ọdún márùn-un, owó ló díjà sílẹ̀ tí mo fi kúrò

Nigba to n tẹsiwaju ninu irinajo iṣẹ tiata naa, Papalolo sọ pe latilẹ loun ti nifẹẹ si orin kikọ .

O ni orin Ogunde loun kọ lasiko ti oun lọ fun ifọrọwanilẹnuwo lati di ara wọn ti wọn fi gba oun si ẹgbẹ naa.

"Emi ni mo maa n ko awọn ipa mi-in to ba yẹ ki baba ko nigba ti a ba n gbaradi, mo si ba wọn ṣiṣẹ pọ fun bii ọdun marun-un ki owo to da ija silẹ laaarin wa."

Alagba Ogunsina sọ pe ere 'Yoruba Ronu' ni awọn lọ ṣafihan rẹ ni Ghana ati Ivory Coast nigba naa, ni wọn ba ni owo Faranse ni wọn yoo fi sanwo fun awọn.

"A yari pe a ko le gba owo Faranse nitori o kere pupọ si owo Naijiria nigba yẹn, a ni ko ni i kopa ninu ere mọ, awọn ero iworan si ti de biba.

"Baba bẹ wa, wọn ni awọn maa fun wa lowo oṣu wa lọjọ keji pelu owo Naijiria, a si gba, a ṣere naa."

O ni Oloogbe Ogunde sanwo naa loootọ, ṣugbọn o ni ki awọn maa lọ, nitori awọn ditẹ mọ ẹgbẹ.

Bi opin ṣe de ba iṣẹ naa ni 1964 niyẹn.

"Bi o tilẹ jẹ pe Jacob ti ku, àmọ́ èmi ati Aderupoko ṣi n rira daadaa, a si jọ n lọ ode pẹlu"

Nipa bo ṣe pade Oloogbe Jacob ati Aderupoko, Papilolo sọ pe ọdọ Oloogbe Ola Omonitan tawọn eeyan mọ si Ajimajasan lawon ti pade.

Lọdọ rẹ lo ni awọn ti n da ti awọn naa ṣe to fi di pe awọn n ṣere fun ileeṣẹ tẹlifiṣan, ti awọn si tun n ṣe awo rẹkọọdu igba naa.

Baba ẹni ọdun marundinlaadọrun-un (85) naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe Jacob ku, oun ati Aderupoko ṣi n rira daadaa, awọn si jọ n lọ ode pẹlu.

Lara awọn agba akọrin to ni awọn jọ lo igba ni: King Sunny Ade, Ẹfanjẹliisi Ebenezer Obey, Oloogbe Epo Akara, Sir Sina/Adewale, Dele Abiodun, Toyin Ajagun ati bẹẹ bẹẹ lọ.