Obasanjo ṣàlàyé ìdí tí kò fi ti El-Rufai lẹ́yìn láti di ààrẹ ní 2007

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Onikun lo mọ ika, ajẹhun lo mọ ọwọ ara rẹ ẹ pọn la.

Oloye Olusegun Obasanjo, aarẹ Naijiria tẹlẹ, ti ṣalaye idi ti ko fi ṣe atilẹyin fun Nasir-El-Rufai, gomina Kaduna nigba kan lati di aarẹ Naijiria ni 2007.

Ilu Abeokuta ni Obasanjo ti sọ aṣiri naa ni ana ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2025,lẹyin ọdun mejidinlogun.

Àì tó ojú ú bọ́ El-Rufai ni mi o ṣe tì í lẹ́yìn kó di ààrẹ lẹ́yìn mi ni 2007

Nigba to n ṣalaye idi naa, Obasanjo sọ pe minisita eto irinna tẹlẹ, Osita Chidoka, to jẹ ọrẹ El-Rufai beere iranlọwọ oun lati jẹ ki El-Rufai di aarẹ lẹyin toun ba fi ipo silẹ.

Osita Chidoka yii naa wa nibi eto ọhun, Obasanjo kọju si I, o ni:

"Nigba ti mo fẹ kuro nijọba, o n gbiyanju (Chidoka) pe ki ọrẹ oun, El-Rufai, gba ipo lọwọ mi."

Obasanjo tun kọju si Chidoka, o beere pe "Abi bẹẹ kọ?"

Chidoka si fi ori dahun pe bẹẹ ni.

Lẹyin naa ni Obasanjo sọ pe oun ko gba lati mu El-Rufai depo aarẹ nitori oun ri i pe ko ti i to oju u bọ.

"Mi o da a lohun. O pada beere lọwọ mi pe ki lo de ti mi o gba ẹni toun ni ko lọ fun ipo aarẹ wọle, mo si sọ fun un pe El-Rufai ni lati dagba nibi to ti yẹ, ko to oju u bọ bo ṣe yẹ."

Aarẹ tẹlẹ naa sọ pe Chidoka funra rẹ pada mọ pe El-Rufai ko kaju ẹ, lẹyin ti oun ti kuro nijọba tan, nigba to ri awọn nnkan ti Nasir n ṣe.

O ni Chidoka pada waa ba oun, o si sọ foun pe bo ṣe ri gẹlẹ loun sọrọ naa, pe El-Rufai ni lati dagba nibi to ti yẹ loootọ.

Obasanjo fi kun un pe ẹkọ ṣe pataki lati jẹ adari, o ni ninu oṣelu nikan loun ti ri i ti awọn eeyan ki i kọ ẹkọ idari rere.

Aarẹ tẹlẹ naa sọ pe awọn adigunjale gan-an n gba ẹkọ, nitori oun ti gbọ ọ ri pe awọn ole maa n gba idanilẹkọọ idari lẹnu iṣẹ wọn.

Lasiko ti Obasanjo wa nipo aarẹ naa, El-Rufai lo wa nipo Adari lẹka okoowo, o si tun pada di minisita ilu Abuja laaarin 2003 si 2007.

Ṣugbọn Obasanjo kọyin si El-Rufai, o si ṣatilẹyin fun Oloogbe Umar Yar'Adua, ẹni to di aarẹ ṣugbọn to papoda ni 2010.

Nibi ipade ti Obasanjo ti sọrọ yii, awọn eeyan nla-nla lorilẹede yii lo wa nibẹ.

Lara wọn ni Oba Olowu ti ilu Owu, Oba Saka Matemilola; Senato to n ṣoju Aarin Gbungbun Ogun; Shuaibu Salis; Olota ti ilu Ota; Oba Adeyemi Obalanlege ati bẹẹ bẹẹ lọ.