You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tinubu gbọdọ̀ sọ ìdí tó fi yọ àwọn ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun Naijiria nípò, ẹgbẹ́ òṣèlú ADC yarí
Ẹgbẹ oṣelu alatako, ADC, ti ke pe Aarẹ Bola Tinubu lati sọ idi to fi yọ awọn ọga agba olori ileeṣẹ ologun Naijiria nipo.
Ẹgbẹ oṣelu ADC sọ pe loootọọ ni Tinubu lagbara lati yọ awọn ọga agba ologun naa nipo, amọ, ẹgbẹ naa ni bi aarẹ ti kede iyọnipo awọn ọga agba ologun naa mu imura dani; papaa julọ lẹyin iroyin kan to sọ pe awọn ologun gbiyanju lati ditẹ gbajọba rẹ.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu ADC, Bolaji Abddullahi, sọ ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ''ojuṣe ijọba apapọ ni lati ṣalaye fun araalu nnkan to ṣẹlẹ gan an.
''Gẹgẹ bi ẹgbẹ osẹlu alatako, nnkan ti a fẹ ni pe ki eto ijọba awarawa ọrilẹede Naijiria fẹsẹ mulẹ daadaa.
Ominu n kọ wa pẹlu awọn nnkan to ti ṣẹlẹ lawọn orilẹede bii Chad ati Niger to wa layika Naijiria.''
Lọjọ Ẹti to kọja ni Tinubu yọ olori ileeṣẹ ọmogun lapapọ Naijiria, Ọgagun Christopher Musa nipo.
Ọgagun Olufemi Oluyede to jẹ olori ileeṣẹ ọmogun oriilẹ tẹlẹ ni aarẹ fi rọpo Ọgagun Musa to yọ nipo.
Ọgagun W. Shaibu ni Tinubu yan gẹgẹ bi olori ileeṣẹ ọmogun oriilẹ tuntun, nigba ti Ọgagun S.K. Aneke di olori ọmogun ofurufu tuntun.
Ọgagun I. Abbas ni olori ọmogun oju omi tuntun ti Aarẹ ṣẹṣẹ yan sipo.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti iroyin kan sọ pe awọn ọmogun kan gbiayanju lati ditẹ gbajọba Aarẹ Tinubu.
Amọ, ileeṣẹ aarẹ ati ileeṣẹ ologun Naijiria sọ pe irọ to jina si oootọ ni iroyin naa.
Eyi lo jẹ ki ẹgbẹ oṣẹlu ADC maa kọminu lori bi Aarẹ Tinubu ṣe yọ awọn olori ileeṣẹ ologun nipo.
''Lai fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iroyin to jade wi pe awọn ologun kan gbiyanju lati ditẹ gbajọba, o ti han gbangba pe ijọba Tinubu n kẹti si ariwo ọja.
Ijọba Tinubu ko yọ awọn olori ileeṣẹ ologun nipo lori bi eto abo ti mẹhẹ kaakiri orilẹede Naijiria.
Yiyọ awọn ọga agba ileeṣẹ ologun nipo lai sọ ohun to ṣẹlẹ gan an yoo tubọ jẹ kawọn eeyan maa gbe iroyin ofege kiri nipa ọrọ iditẹgbajọba to jade ninu iroyin laipẹ yii ni,'' ẹgbẹ oṣelu ADC lo sọ bẹẹ.