Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó jí ara rẹ̀ gbé parọ́ gbowó kó sọ́wọ́ ọlọ́pàá nípínlẹ̀ Ogun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹ̀ka iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó ń rí sí ìwádìí ní ìpínlẹ̀ Ogun ti nawọ́ gán ọkùnrin, ẹni ọdún méjìdínlógójì kan, Kacou Alleby tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Ivory Coast fẹ́sùn pé ó jí ara rẹ̀ gbé.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà, Benjamin Hundeyin fi síta sọ pé àwọn rí àtẹ̀jíṣẹ́ láti iléeṣẹ́ National Central Bureau ti ìlú Abuja ní orúkọ orílẹ̀ èdè Côte d'Ivoire lórí pé wọ́n ń wá ọkùnrin náà.

Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án ni wọ́n ní Alleby di àwátì, tí àwọn tó jigbé sì kàn sí àwọn ẹbí rẹ̀ pẹ̀lú àwòrán àti fídíò láti fi hàn pé àwọn ń fi ìyà jẹ́ ní àhámọ́ àwọn àti pé wọ́n nílò láti san owó kó tó rí ìtúsílẹ̀.

Hundeyin ṣàlàyé pé ní agbègbè Matogun ní ìpínlẹ̀ Ogun ni wọ́n ti ṣàwárí àwọn afurasí náà níbi tí ọwọ́ ti tẹ obìnrin kan, ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, Angela Arisa tí òun náà jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Ivory Coast.

Ó ní bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe gbọ́ pé wọ́n jí ọkùnrin náà gbé ni ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ti pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àwárí rẹ̀ ní kíákíá.

Ó sọ pé èyí lọ mú àwọn tọpinpin àwọn afurasí náà sí agbègbè Matokun ní ìpínlẹ̀ Ogun tí ọwọ́ sì tẹ Angela Arisa níbẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà sọ pé afurasí náà ló mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé kan ní agbègbè Olambe níbi tí wọ́n ti rí Alleby, tí wọ́n sì tu sílẹ̀ láì farapa.

Ó fi kun pé ìwádìí fi hàn Alleby àti Angela ni wọ́n jọ lẹ̀dí àpòpọ̀ láti parọ́ pé wọ́n ji gbé láti fi gba owó lọ́wọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ tó wà ní Abidjan.

Ó ní wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe fídíò irọ́ èyí tí wọ́n fi ránṣẹ́ sáwọn ẹbí Alleby láti fi lè ri pé wọ́n tètè wá owó nígbà tí wọ́n bá ri pé wọ́n ń fìyà jẹ ẹ́.

Ó sọ pé ìwádìí ṣì ń lọ láti ṣàwárí àwọn míì tí wọ́n jọ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ibi náà.

Bákan náà ló fi kun pé ìwà ọ̀daràn tó ní ìjìyà lábẹ́ òfin Nàìjíríà ni kí èèyàn parọ́ pé wọ́n jí òun gbé tó sì jẹ́ pé òun ló wà nídìí rẹ̀.

"Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, Kayode Egbetokun ṣèkìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá lọ́wọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀ yóò fojú winá òfin nítorí kìí ṣe pé wọ́n ń fojú tẹ́mbẹ́lú ètò ààbò ìlú nìkan bíkòṣe pé wọ́n ń ba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lójú jẹ́."

Ìwà jíjí ara ẹni gbé ti ń wọ́pọ̀ ní Nàìjíríà táwọn onímọ̀ nípa ètò ààbò sì ń ṣèkìlọ̀ pé ìwà bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ fífi ohun èlò àwọn ọlọ́pàá ṣòfò nìkan bíkòṣe pé kò ní jẹ́ kí wọ́n máa gba àwọn aráàlú gbọ́ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi bá wáyé.

Nínú oṣù Kẹjọ ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo tẹ ọkùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n kan, Bello Azeez tó parọ́ pé wọ́n jí òun gbé láti fi gba owó lọ́wọ́ àwọn ẹbí rẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Ondo, Olushola Ayanlade sọ pé Azeez tó jẹ́ ọmọ ìlú Ipele ní ìjọba ìbílẹ̀ Owo parọ́ ìjínigbé rẹ̀ nígbà tí bàbá rẹ̀ kọ̀ láti fún-un ní owó N500,000 láti fi san gbèsè.