You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló dé tí ẹbí Mohbad tún n wá àwọn ẹlẹ́rìí síi lórí ikú rẹ̀?
Igbimọ agbẹjọro mọlẹbi gbajugbaja akọrin takasufee to ti doloogbe, Ilerioluwa Oladimeji Aloba, tọpọ eeyan mọ si Mohbad ti sọ pe awọn yoo nilo awọn ẹlẹrii sii lati wa ṣalaye awọn ohun ti oju wọn to nipa iku rẹ.
Wọn ni ọrọ iku Mohbad gbẹgẹ pupọ leyi tawọn fi gbọdọ mọ ohun ti wọn yoo sọ sita fun araalu.
Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe, ọkan lara awọn olori igbimọ ọhun, Taiwo Odumosu sọ ninu atẹjade to fi sita, pe awọn ẹri ti wọn ba gba, ọlọpaa lo yẹ ki wọn ko o fun, kaka ki wọn fi sita fawọn eeyan.
Bakan naa lo tun rọ awọn eeyan lati jade wa sọ ohun ti wọn mọ nipa iku Mohbad, lati le ran iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ
“Bi a ba wo bi awọn ohun to rọ mọ iku Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad), ati awọn ohun ti wọn ti gbe sita fawọn eeyan, leyi to jẹ pe ọwọ ọlọpaa nikan lo wa, awa igbimọ agbẹjọro mọlẹbi Aloba yoo fẹ lati rọ ẹnikẹni to ba ni awọn ẹri to jọju, to si ṣe pataki lọwọ, lati le jẹ ki iṣẹ iwadii yọri si rere nipa iku ọmọ wa, ki wọn wa ba igbimọ agbẹjọro lati fi to wa leti.
“Ẹ tun le kan si awọn ọlọpaa naa lati fi to wọn leti pẹlu fun aabo ẹlẹri ati afurasi,” atẹjade ọhun ṣalaye.
Odumosu sọ pe oniṣẹ iwadii coroner ti pe fun ẹlẹrii, to si ni awọn mọlẹbi n wa iranlọwọ lati ko ẹri jọ lati le mọ ohun to ṣeku fa iku aitọjọ Mohbad.
“Ẹ dakun, ẹ jẹ ko di mimọ pe Joseph Aloba ko wa ibaṣepọ to dan mọnran kankan lasiko yii. Gbogbo ohun to n fẹ ni lati ri idi okodoro ohun ṣeku pa ọmọ rẹ
Ile-ẹjọ iwadii coroner nikan lo lẹtọọ lati sọrọ lori iwadii ti yoo mu wa yọri ninu ẹjọ to n lọ nile-ẹjọ,” o fi kun atẹjade naa.
Ṣoki nipa Mohbad
Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Mohbad nigba to ku lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023.
Iku rẹ mu awuyewuye dani lori ayelujara, ti ọpọ si n tọka si ẹni to ni ileeṣẹ orin to n gbe e sita tẹlẹ, Naira Marley.
Oṣu Keji, ọdun 2022, ni Mohbad kuro nileeṣẹ to n gbe orin sita, Marlian Music to jẹ ti Naira Marley.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 gbe igbimọ oluwadii ẹlẹni mẹtala dide lati ṣe iwadii iku onkọrin ọhun.
Iku rẹ lo tun fa bi awọn ọlọpaa ṣe fi kele ofin gbe Naira Marley ati gbajumọ kan ipinlẹ Eko, Balogun Eletu, ti wọn tun n pe ni Sam Larry, ati awọn miran.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 ni wọn lọ wu oku Mohbad fun ayẹwo lati mọ iru iku to pa a.