Wo ohun tí bíṣọ́ọ̀bù Mathew Kukah sọ nípa àwọn adarí Naijiria lásìkò ọdún Àjíǹde

Biṣọọbu ijọ Katoliki Sokoto, Mathew Kukah ti sọko ọrọ si awọn adari Naijiria, to si juwe wọn gẹgẹ bii ọmuti ti ko mọ ọna ile rẹ mọ.

Kukah lo fi ọrọ naa lede ninu ọrọ ikini rẹ si awọn ọmọ Naijiria lasiko ọdun Ajinde.

O ni lati ọgọta ọdun o le ti Naijiria ti gba ominira, awọn adari rẹ ti kuna lati fi orilẹede naa le ọna ti yoo maa tọ.

Ninu ọrọ naa ni biṣọọbu ọhun ti da aba ohun ti awọn aṣaaju Naijiria le ṣe lati gbe Naijiria de ebute ogo.

Kukah sọ pe “ Awọn adari yan lati maa jẹ mudumudun dipo ki wọn gbaawẹ, ohun ti a gbin lana ni a jere lonii.

“Fun ọgọta ọdun o le, niṣe lawọn adari wa dabi ọmutin ọkunrin ti ko mọ ọna ile rẹ mọ.

“Iwa ajẹbanu ati ọdunmọdun ti tan kalẹ si wa lara bii arun jẹjẹrẹ, eyii to mu ki ilu wa dori kodo.

“Amọ ṣa, ọdun Ajinde jẹ asiko mii fun wa lati ronu jinlẹ nipa ọna to yẹ ki a gba, a ni lati ronu jinlẹ lati wo boya inira Golgotha ti a n jẹ yii le gbe wa de ilẹ ileri.

“Ijọba gbọdọ gba awọn eeyan siṣẹ lai ṣe eto igbanisiṣẹ naa ni bonkẹlẹ, o si gbọdọ pa ọrọ ẹlẹyamẹya ti sẹgbẹ kan.”

Alufa Kukah pari ọrọ rẹ pe ijọba tun gbọdọ wa atunṣẹ si iṣoro eto abo to n koju Naijiiria lasiko yii.