Ogunde ló sọ fún Kunle Afolayan láti fi mí ṣe Baṣọ̀run nínú sinimá Anikulapo - Owobo

Ogunde ló sọ fún Kunle Afolayan láti fi mí ṣe Baṣọ̀run nínú sinimá Anikulapo - Owobo

Orisa ti a ba n sin, ti a ko ba fi han ọmọde, ko ni pẹ parun, bẹẹ si ni ọmọ kii da ipele iya rẹ, ko si asọ da.

Awọn owe yii lo jẹ ti Owobo Ogunde, ẹni to jẹ ọmọ gbajumọ osere tiata, Herbert Ogunde, ẹni to da ere sise silẹ .

Ilu ọba ni Owobo fi se ile, lai maa kopa ninu ere tiata gẹgẹ bi baba rẹ ti n se, ti pọ eeyan ko si mọ dunju lagbo tiata.

Amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn eeyan ri Owobo, ẹni to jọ baba rẹ, Herbert Ogunde, ninu sinima Anikulapo ti gbajumọ osere tiata, Kunle Afolayan sẹsẹ gbe jade.

Owobo Ogunde si lo se Basọrun ninu sinima naa.

Ọpọ eeyan lo n beere pe nibo ni ọmọ baba Ogunde yii wa lati ọjọ yii, ti ko si tẹsiwaju pẹlu isẹ tiata ti baba rẹ fi silẹ.

BBC Yoruba wa Owode Ogunde kan lati mọ Ọna nipa iru eeyan tojẹ, ibi to ti wa lati ọjọ yii, bi oun ati Afolayan se pade ati afojusun rẹ fun ere tiata.

Lẹyin iku baba mi Ogunde, mo gba ilu oyinbo lọ lọdun 1992, ti n ko si sere tiata mọ titi digba ti mo se Anikulapo – Owobo Ogunde

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Owobo Ogunde ni oun maa n kopa ninu ere tiata lasiko ti baba oun, Herbert Ogunde wa nile aye.

Amọ lẹyin ti baba naa ku tan lọdun 1990, ni oun gba ilu London lọ lati maa gbe lọdun 1992, ti oun ko si kopa ninu ere tiata mọ lati igba naa.

“Ilu London ni wọn bi mi si lasiko ti baba wa sere nibẹ, idi ree ti mo fi gba ilu naa lọ lati maa lọ gbe lẹyin ti baba ku tan.

N ko si sere tiata mọ titi ti mo fi pade Kunle Afolatyan nilu London, to si tun fi ere tiata lọ mi.”

“Kunle Afolayan ni baba mi Ogunde lo sọ fun oun pe ki oun fi mi se Basọrun ninu sinima Anikulapo”

Nigba to n salaye bi oun ati Kunle Afolayan se pade ninu London, Owobo ni ọmọ oloogbe Isho Pepper, Bola Ogunsola lo mu oun ati Kunle mọra ni London.

“Bola Ogunsola lo fi emi ati Kunle Afolayan mọ ara wa lasiko ti a pade lati se ariya.

Nibẹ si ni Kunle ti sọ fun mi nipa sinima Anikulapo to fẹ gbe jade, to si ni ọkan oun mu mi lati se Basọrun ninu sinima naa.

Bakan naa lo oun ri baba mi Ogunde, to si sọ fun oun pe emi owobo, lo gbọdọ mu lati se Basọrun ninu sinima Anikulapo to fẹ se.

O ni baba mi sọ pe n ko gbọdọ kọ lati kopa, idi ree ti mo fi gba si lẹnu.”

Owobo Ogunde tẹsiwaju pe oun mọ ohun to wa laarin baba oun ati baba Kunle Afọlayan nitori ọrẹ timọtimọ ni awọn mejeeji.

“Baba Kunle ati Baba mi ni wọn dijọ se sinima Ayanmọ lọdun 1986 nilu Ososa, mo mọ baba Kunle daadaa.

Idi si ree ti n ko fi le kọ lati kopa ninu sinima Anikulapo.”

“Mo maa n ri Baba mi Herbert Ogunde loju ala, gbogbo ohun to ba mi sọ ni maa se patapata”

Owobo Ogunde, lasiko to n sọrọ nipa baba rẹ, Hubert Ogunde, o ni oun si maa n ri baba oun loju ala, to si maa n ba oun sọ awọn ọrọ kan.

“Mo si n ri baba mi loju ala, o ni ni awọn ohun to n sọ fun mi.

Gbogbo ohun to n sọ fun mi naa ni maa si se patapata nitori o jẹ mi logun, ki Ọlọrun fun mi se.

Awọn ohun to jẹ mi logun julọ ni pe ka se isẹ tawọn baba wa fisilẹ, ti wọn si gbe le wa lọwọ.”

“Awọn eeyan n ri ọla baba mi lara mi lati igba ti mo ti se sinima Anikulapo, ọpọ osere ti n pe mi si ere wọn”

Owobọ tẹsiwaju pe lati igba ti oun ti se ere sinima Anikulapo ni ọpọ eeyan ti n da oun mọ lorilẹede Naijiria ti nilu Ọba ti oun n gbe.

“Ọpọ eeyan lo n da mi duro loju popo, ti wọn si n pariwo orukọ mi, koda, omiran yoo fi mọto rẹ silẹ loju titi lati ki mi.

Ọpọ awọn osere tiata miran lo ti n pe oun lati wa kopa ninu ere sinima wọn, ti oun si ti setan lati maa tẹsiwaju ninu isẹ tiata.

“A setan lati gbe orilẹede wa ati asa wa larugẹ, ohun ti emi fẹ ti ara bọ niyẹn, gẹgẹ bi baba mi ti se.

Mo dagba sinu isẹ tiata ni, maa dẹ se, maa si tun se ju bẹẹ lọ, eyi ti yoo wu baba mi lori lati gbosuba fun mi.”