Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣúná báńkì àpapọ̀ CBN - Tinubu

Oríṣun àwòrán, Other
Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe iwadii to jinlẹ ti n waye lori banki agba Naijiria, Central Bank. Bakan naa lo sọ pe atunto yoo waye laipẹ lori ilana ti wọn n gba san owo oṣu àwọn oṣiṣẹ ijọba.
Ninu atẹjade ti olubadamọran fun aarẹ lori eto iroyin ati ikede, Ajuri Ngelale, fi sita, Aarẹ Tinubu sọ ọrọ naa lasiko ipade kan to ṣe pẹlu Aarẹ Banki Agbaye, Ọgbẹni Ajay Banga lọjọ Ẹti nile ijọba l'Abuja. Tinubu sọ pe o ṣoro fun oun lati gba iye osisẹ ti akọsilẹ wa pe o n gba owo oṣu gbọ, nitori pe oun ti ni iru iriri bẹẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ. "Awọn atunto naa jẹ ara ọna lati din gbogbo ọna ti owo n gba ṣofo. " Awọn atunto naa yoo da lori bi a ṣe n ṣiṣẹ, ayipada iwa ati eto idanilẹkọ fun awọn eniyan wa." Ajuri Ngelale sọ pe aarẹ parọwa fun banki naa lati ma ri Naijiria gẹgẹ bi ọkan pataki lawujọ agbaye, dipo ọrọ aje to n tiraka. Yatọ si eyi, aarẹ tun bẹ banki naa fun iranlọwọ lori mimu adinku ba oṣi.
Bakan naa lo tun beere fun atilẹyin lati din inira ti yiyọ owo iranwọ 'subsidy' ni ẹka gbogbo, n ni lara awọn ọmọ Naijiria to ku kaato fun ku.
Ninu ọrọ ti ẹ naa, aarẹ banki agbaye, Ọgbẹni Banga gboriyin fun awọn igbesẹ ti Tinubu n gbe lori ọrọ aje Naijiria, o si tun ṣe ileri pe banki naa yoo fi ọwọ sowọpọ pẹlu Naijiria pẹlu gbogbo nnkan to wa ni ikapa rẹ.








