You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òkú Gómìnà Akeredolu tí balẹ̀ sí Nàìjíríà láti Germany
Oku Gomina télẹ nipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ti balẹ si orilẹede Naijiria.
Ọkọ baalu to gbe oku naa balẹ ni dede ago mẹta abọ ni ọjọ karun un oṣu kinni ọdun 2024.
Lati orilẹede Germany ni wọn ti gbe oku naa wa si orilẹede Naijiria,
Iyawo Gomina tẹlẹ, Betty Anyanwu-Akeredolu, awọn ọmọ ati mọlẹbi ti Ọjọgbọn Wole Akeredolu lewaju fun lo lọ pade oku naa.
Lara awọn to wa pẹlu wọn Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, ẹni ti ọga agba fun osisẹ, Tayo Ayinde soju, Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun, ẹni ti Akọwe ijọba nipinlẹ Ogun, Tokunbo Talabi soju fun un pẹlu.
Awọn yooku ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo,Ade Adetimehin, ọmọ ile igbimọ aṣofin, Gboyega Adefarati, awọn igbimọ ijọba eti ti akọwe ijọba, Ọmọọba Oladunni lewaju fun wa pẹlu awọn to tẹwọgba oku naa.
Omije bo ọpọ awọn eeyan to wa nibẹ lasiko ti wọn gbe oku naa kalẹ lati ninu baalu.
Gomina Akeredolu jade laye ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2023 niluu Germany.
Wọn yoo gbe oku rẹ si ile igbeoku si titi eto isinku yoo fi waye