Ramon Adedoyin gbé àkọtun ìgbésẹ̀ lórí ìdájọ́ ikú tílé ẹjọ́ dá fun lórí ikú Timothy Adegoke

Adari ileeṣẹ ile itura Hilton Hotels ni ile -ifẹ nipinlẹ Osun, Dokita Ramọn Adedoyin ti gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ lẹyin ti adajọ da ẹjọ iku fun lori iṣekupani akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke.

Ileẹjọ giga nipinlẹ Osun lo da ẹjọ pe ki wọn yegi fun nitori o lọwọ ninu iku arakunrin naa to sun si ile itura rẹ.

Ti a ko ba gbagbe, adajọ Adepele Ojo lo ran Adedoyin ati oṣiṣẹ rẹ meji ti wọn gbe oku naa kuro ni ile itura naa, Adeniyi Aderogba ati Oyetunde Kazeem pe ki wọn yẹ igi fun.

Bakan naa ni adajọ ni ijọba ti gbegile ile itura naa, ti o si ti da ti ijọba.

Adajọ tun ni ohun ini Adedoyin ni wọn yoo fi ran awọn ọmọ Adegoke lọ si ileẹkọ titi wọn yoo fi jade fasiti.

Amọ adajọ naa fi awọn oṣiṣẹ mẹta silẹ, Magdalene Chiefuna, Oluwole Lawrence ati Adebayo Kunle ki wọn maa lọ ni alaafia, ti akọwe to wa ni ibi isẹ naa si gba idajọ ẹwọn ọdun meji fi jura.

Nibayii ni Ramon Adedoyin ti ni oun ko faramọ idajọ iku naa, to si ti gba ileẹjọ naa.

Ọkan ninu awọn adajọ Adedoyin, Adajọ agba Kunle Adegoke lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Bakan naa lo ni ileẹjọ kotẹmilọrun ni ilu Akure, nipinlẹ Ondo ni wọn gbe ẹjọ naa lọ.