You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọde bíi 100 ló wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó rì, èyí tó gbẹ̀mí èèyàn 78
Awọn ti ori ko yọ ninu ijamba ọkọ oju omi kan to rì ni Greece, ti sọ pe o to ọgọrun ọmọde to wa ninu ọkọ naa.
Ko din ni oku eeyan mejidinlọgọrin ti wọn ti ri ko jade ninu ijamba naa, amọ o si ṣeeṣe ki ọpọ eeyan di awati nitori pe iroyin ní o to ẹẹdẹgbẹrin le aadọta eeyan (750) to wa ninu ọkọ oju omi naa.
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi si n wa gbogbo agbegbe naa lati wo boya wọn o ri awọn eeyan yọ jade.
Iroyin sọ pe òfìfo ni ọkọ oju omi naa kuro ni Egypt, to si duro ni ibudokọ omi Tobruk ni Libya lati gbe awọn atipoo to n lọ si Italy.
Awọn dokita to n tọju awọn ti wọn ko jade ninu omi laaye sọ pe obinrin ati awọn ọmọde pọ̀ ninu ọkọ naa.
Dokita agba kan ni ileewosan Kalamata General Hospitak sọ fun BBC pe o to ọgọrun ọmọde to wa ninu ọkọ.
Dokita miran, Manolis Makaris, sọ pe yoo to ẹgbẹta eeyan to ku ninu ijamba naa, pẹlu nnkan ti awọn ti wọn n tọju nileewosan sọ.
Bo tilẹ jẹ pe BBC ko tii le fidi eyi mulẹ, ajọ alaanu Save the Children, sọ pe lootọ ni paapaa nitori ọrọ ẹri ẹnu awọn ti kò kú.
Agbẹnusọ ijọba orilẹ-ede Greece, Ilias Siakantaris sọ pe awọn ko mọ iye eeyan to wa ninu ọkọ, ṣugbọn nnkan to daju ni pe awọn to n ṣe fayawọ eeyan ma n ko ọpọlọpọ.
Diẹ lara ẹbi awọn eeyan to di awati ti de si ilu Kalamata lati wa eeyan wọn.
Ọkunrin kan, Aftab to sare wa lati UK sọ pe mọlẹbi oun bii mẹrin lati Pakistan, lo wa ninu ọkọ̀ oju omi naa.
Ọkunrin kan ara Syria to n gbe ni Netherlands, Kassam Abozeed sọ pe iyawo oun ati aburo rẹ kan ṣi jẹ awati.
Ileeṣẹ amohunmaworan orilẹ-ede Greece sọ pe eeyan mẹsan-an ati ọpọlọpọ ọmọ orilẹ-ede Egypt ni ọwọ ti tẹ fun ẹsun pe wọn lọwọ ninu ṣiṣe fayawọ eeyan.
Irinajo ọkọ oju omi naa ni wakati-wakati
08:00 Awọn ẹṣọ alaabo ori omi ni Greece sọ pe awọn gba ipe lati ọdọ awọn alaṣẹ Italy, nipa ọkọ oju omi kan to ko awọn atipoo
11:00 - Awọn oṣiṣẹ alaabo ni awọn kàn si ọkọ oju omi naa, amọ ko beere fun iranlọwọ
12:17 – 15:34 Ajọ kan to n ri si ipe pajawiri sọ pe ọpọlọpọ ipe fun iranlọwọ jáde lati inu ọkọ oju omi naa
15:00 - Ọkọ oju omi akẹru kan ko omi ati ounjẹ fun awọn to wa ninu ọkọ to rì
19:40 – 22:40 Ọkọ oju omi awọn oṣiṣẹ alaabo Greece rin nitosi ọkọ oju omi to ri, ṣugbọn ko ṣakiyesi pe irin rẹ ko lọ daadaa
22:40 - Ẹnjinni ọkọ oju omi naa ko ṣiṣẹ mọ
23:04 - Ọkọ oju omi naa yii danu, o si rì
04:00 - Awọn ọkọ oju omi bẹrẹ iṣẹ idoola
Ajọ kan to ma n gba ipe pajawiri lati ọdọ awọn atipo lori omi, Alarm Phone, sọ pe awọn oṣiṣẹ alaabo ti mọ nipa iyọnu to ba ọkọ oju omi naa fun ọpọ wakati, ki wọ̀n o to ran iranlọwọ si wọn.
Amọ agbẹnusọ ileeṣẹ alaabo ori omi naa, Nikos Alexious sọ pe awọn gbiyanju ki ọkọ oju omi naa beere fun iranlọwọ, tabi ko duro to ba nilo ki awọn ba a doola awọ̀n eeyann.
Diẹ lara awọn to yè sọ pe nigba ti wahala de, awọn oṣiṣẹ alaabo sọ fun ọkọ awọ̀n pe ko tẹle wọn, ṣugbọn ọkọ naa ko le ṣe bẹẹ.
“Lẹyin naa ni awọn oṣiṣẹ alaabo ju okun lati fi fa a, amọ niṣe ni ọkọ wa bẹrẹ si ni fì si ọtun, si osi.
“Ko pẹ̀ẹ́ to fi rì sinu omi.”