Wo ipa tí áṣẹ CBN fún àwọn báńkì olókoòwò láti ta dọ́là ní iye tó wù wọ́n yóò ní lórí rẹ

Banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN ti kede pe awọn banki olokoowo ni abẹle ni yoo maa sọ iye ti wọn ba fẹ ta dọla si Naira bayii, kii ṣe oun ni yoo maa sọ gbedeke iye pasipaarọ naa mọ.

Ki o to di asiko yii, CBN ni o ma n fun awọn banki ni gbedeke iye ti wọn yoo ma ta dọla si Naira.

Eyi tumọ si pe awọn banki lee se pasipaarọ Naira si Dọla ni iye to ba wu wọn.

"Ofin tuntun ti banki CBN se yii tumọ si pe ijọba apapọ ti yọwọ kuro ninu ipese owo iranwọ lori pasipaarọ Naira si Dọla"

Iroyin ni awọn banki kan ti n ta dọla laarin N699 si N750 bayii, eleyii tumọ si pe awọn banki kọọkan naa lee sọ iye ti wọn fẹ ta ti wọn.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti aarẹ Tinubu ṣeleri lati ri pe pasipaarọ owo Naira si Dọla bara dọgba lawọn banki ati lọja okunkun, ti iye pasipaarọ naa si se ọkan kaakiri.

Onimọ nipa eto ọrọ aje kan ti salaye fun BBC nipa ohun ti igbesẹ isọkan pasipaarọ iye owo Naira si Dọla naa tumọ si.

O ni ṣaaju ni CBN ti n lo owo dola ni apo aṣuwọn ijọba, ti wọn si n taa fun awọn eniyan kan ni N411, nigba to yẹ ko jẹ N700 si 750.

Amọ o ni nibayii ti ijọba ti yọwọ ipese owo iranwọ lori pasipaarọ Naira si Dọla bayii awọn ipa to pọ ni eyi yoo ni lori ọrọ aje wa.

Bakan naa, o ni igbesẹ yoo ni ipa lori igbaye-gbadun awọn ọmọ Naijiria lati oke de isalẹ.

Ki ni igbesẹ banki CBN tuntun yii tumọ si, bawo lo si se kan ọ?

  • Awọn ijọba ipinlẹ ti ko lee san owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ wọn tẹlẹ yoo le san bayii
  • Nibayii awọn ijọba ipinlẹ yoo ma ri dọla gba ni iye to jẹ gan an.
  • Eyi tumọ si pe awọn kan ko ni maa ri dọla gba ni ọna alumọkọrọyi mọ, ti yoo si wa fun awọn to nilo rẹ
  • Bakan naa ni awọn onibara lati ilẹ okeere to ba fẹ ṣe idokowo pẹlu Naijiria yoo ri ṣe ni iye to wu wọn
  • Awọn ohun alumọni ni Naijiria yoo ni iye lori, ti ọrọ aje ni Naijiria yoo si gbooro si
  • Bakan naa ni iye owo Naira ni Naijiria yoo ni iye lori si, ju ti tẹlẹ lọ
  • Ko ni si magomago nipa rira dọla mọ
  • O ṣeeṣe ki iye ti wọn n ra epo bẹntirol walẹ si
  • Bakan naa ni ipese iṣẹ yoo wa nitori awọn onisowo yoo wa si Naijiria lati da ileeṣẹ silẹ.