You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mùsùlùmí ni ààrẹ àti igbákejì rẹ̀ lóòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbàgbé wa-CAN Àríwá
Awọn agbaagba ẹgbẹ onigbagbọ, Christian Association of Nigeria (CAN), ẹka ti iha Ariwa Naijiria ti sọ pe iṣakoso Aarẹ Bola Tinubu ati Kashim Shettima ti i ṣe igbakeji rẹ ko gbagbe awọn, bo tilẹ jẹ pe musulumi ni awọn mejeeji.
Nibi ipade atigbadegba ẹgbẹ naa ni Alaga CAN Oke Ọya, Yakubu Pam, ti sọrọ yii lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.
Alaga CAN Ariwa sọ pe bo tilẹ jẹ pe ero ọkan awọn tẹlẹ ni pe ki Igbakeji aarẹ jẹ Kristẹni, ṣugbọn ni bayii, o ti han pe iṣakoso Tinubu ko gbagbe awọn pẹlu eto rẹ.
O ni kedere lo foju han pe iṣejọba yii n ro ti awọn Kristẹni Oke Ọya mọ tiwọn.
"Ni temi, ohun to ṣe pataki ju ni ijọba to ko gbogbo ilu mọra. Bo ṣe jẹ pe Musulumi ni awọn mejeeji to, a ti ri awọn apẹẹrẹ ibi ti wọn ko ti gbagbe awa naa."
Alaga CAN Ariwa lo ṣalaye bẹẹ.
Ṣugbọn ṣaa, Alagba Pam sọ pe ohun ti yoo tẹ awọn lọrun ju ni ki aarẹ jẹ Musulumi, ki igbakeji rẹ si jẹ Kristẹni.
"Ti a ba fi da tiwa, a maa fọwọ si i pe ka ni awọn Kristẹni ni awọn ipo kan. Bii ipo igbakeji aarẹ, eyi yoo ṣafihan awọn nnkan mi-in ti orilẹede wa tun ni."
Alaga CAN l'Oke-Ọya lo ṣalaye bẹẹ.
Lori aabo to mẹhẹ lorilẹede yii, Pam sọ pe ohun to yẹ kijọba mojuto gidi ni.
O ni oun gba pe bi Kristẹni ba di igbakeji aarẹ, loootọ, aabo le ma ti i fẹsẹ mulẹ, ṣugbọn awọn n gbadura fun alaafia, ko si sohun to buru nibẹ, bi ero ọkan awọn naa ba wa si imuṣẹ.
Ẹ o ranti pe ariwo gbalẹ gidi nigba ti Aarẹ Bola Tinubu fa Kashim Shettima toun naa jẹ Musulumi kalẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ ni 2023.
Wọn gba ọrọ naa bii ẹni gba igba ọti titi ko too lọ sokun igbagbe.