Tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC kó bá ṣọ́ra, wọ́n ó pàdánù ìdìbo 2023 -Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti se ikilọ fun ẹgbẹ All Progresssive Congress lati ma gbinyanju tabi ni erongba lati gbe asia ẹgbẹ oselu naa fun olujide lati oke ọya, ti wọn o ba fẹ padanu eto idibo lọdun 2023.

Ninu atesita kan to fi si ori ayelujare Facebook re, Akeredolu, ẹni ti o je Alaga fun awọn gomina lapa guusu orile-ede Naijiria, gba ẹgbẹ naa ni iyanju lati mu omo oye ti o gbe asia ẹgbẹ lati guusu orile-ede Naijiria.

“APC gbọdọ di agbara mu o”

“A gbọdọ jẹ ki agbara kan sibi gbogbo lati di agbara Naijiria mu, sugbọn ti a ba kọ, o lewu o.”

“Guusu orilẹ-ede Naijiria lo kan.”

O tẹsiwaju pe asiko Guusu orile-ede Naijiria lo kan lati di aarẹ latari iwe adehun kan ti ẹgbẹ naa bowọlu nibi ìpade gbogbogbo ẹgbẹ APC.

Lara awọn ti o ti kede erongba lati gba asia ẹgbẹ oselu All Progressive Congres lati Guusu orilede yii ni a ti ri Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Gomina Dave Umahi, Sẹnetọ Rochas Okorocha, Ibikunle Amosun, Pasitọ Tunde Bakare, Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo, Nicholas Felix, Kayode Fayemi, Rotimi Amaechi ati bebelo.