You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé òótọ ni pé àwọn ọ̀dọ́ ń torí $40k gé ọmọ ìka ẹsẹ̀ wọn tà? BBC gbé èsì ìwádìí jáde
Ṣe lootọ ni tabi ko ri bẹẹ?
Ibeere ti ẹka to n tan imọlẹ si iroyin arumọjẹ nileeṣẹ BBC gbiyanju lati wa idahun si ree lẹyinti iroyin gbode ni Naijiria e pe awọn eeyan ni Zimbabwe n ge ọmọka ẹsẹ wọn ni $40,000 lati fi wa ọna ọla.
Ẹka ileeṣẹ wa tọ pinipin iroyin yi taa si ri pe lati oju opo kan ni Zimbabwe torukọ rẹ n jẹ Gambakwe lo ti ṣẹ wa.
Ninu apilẹkọ kan ti wọn gbe sita lọjọ kejilelogun oṣu kaarun Gambakwe sọ pe''awọn afurasi Sangoma ni South Afrika n fi owo tabua lọ awọn ọdọ Zimbabwe ti ko niṣẹ lọwọ fun ọmọka ẹsẹ wọn ti wọn ba ge''
Sangoma lorukọ ti wọn n pe babalawo ni orileede South Afrika.
Oju opo iroyin yi so ọrọ to gbe jade mọ ọrọ ojuopo Whatsapp kan ti oju opo naa sọ pe awọn eeyan n gbe kaakiri ni Zimbabwe.
Gẹgẹ bi ojuopo yi ṣe sọ, owo ọmọka tita yi n waye ni ile itaja Ximex Mall to wa ni Harare, olu ilu Zimbabwe.
Lati igba ti ọrọ yi ti jẹyọ lo ti wu iye to si fo de awọn orileede Afrika miran tawọn eeyan orileede Uganda ati Naijiria si bẹrẹ si ni kọ nipa rẹ loju opo Twitter.
Eeyan kan lojuopo Twitter, @joyie7star lati Kampala, Uganda tan iroyin ti ko fẹsẹ mulẹ yi sawọn to n tẹle opo rẹ to le ni ẹgbẹrun mẹfaa
Ni Naijiria ọrọ ti @InnocentZikky fi sita to fẹ oju ọrọ yi juti tẹlẹ lọ lawọn eeyan tan kaakiri ni igba to le ni ẹgbẹrun meji to si pọ debi pe o leni ẹgbẹrun mẹrin laarin wakati mejidinlogun.
Ọrọ Twitter yi ni paapa lo aworan lati ara iroyin ti oju opo Gambakwe kọkọ gbe sita.
Awọn aworan yi ni awọn eeyan n tan kaakiri lati fi kin iroyin ofege yi lẹyin.
Ileeṣẹ redio Kenya 933 KFM naa kọ nipa iroyin yi loju opo Tweeter wọn koda wọn beere lọdọ awọn olugbọ wọn pe ẹya ara wọn wo ni wọn ṣetan lati ta nirtori owo.
Ni tiwọn, ileeṣẹ iwe iroyin Zimbabwe torukọ rẹ n jẹ H-Metro pin ifọrọwanilẹnuwo kan ti wn ṣe pẹlu awọn oniṣowo to sọ pe niṣe lawọn eeyan tawọn ko mọ ri wa n beere bawọn ṣe le ri t'aje ṣe ninu owo tita ẹya ara yi.
Awọn oniṣowo to ba H-Metro sọrọ sọ pe awọn sọ fun awọn eeyan naa pe iroyin ofege lasan ni.
Ẹka to n ṣe iwadii iroyin ofege BBC si tun ṣagbeyẹwo awọn fidio meji kan ti wọn sọ pe awọn to wa ninu rẹ fẹ ta ẹya ra wọn tabi ti wọn si ti taa tan.
A ri pe wọn kii ṣe fidio to fẹsẹ mulẹ, awọn to wa ninu wọn n ṣere ni.
Ninu ọkan ninu awọn fidio yi, niṣe larakunrin kan ṣe bi ẹni pe o fẹ ge ọmọka rẹ ṣugbọn ko si apẹrẹ pe lootọ ni.
Ohun to jọ ni pe o n dapara lati le fi jẹ ki awọn eeyan wo fidio rẹ ni nitori ẹni ti wọn ni wọn ge ọmọka rẹ ninu fidio yi n rẹrin ni.