You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Suzzanne Wenger: Obìnrin òyìnbó tó mọ ojú òrìṣà Osun ju ọmọ Yorùbá lọ
Ni ilẹ kaarọ oojiire, ẹsin ibilẹ tabi iṣẹṣe rinlẹ lati atijọ, ohun si lo jẹ ẹsin abalaye tawọn baba nla wa tẹwọgba lati fi maa sin Olodumare.
Amọ, nigba ti awọn oyinbo alawọ funfun de, ẹya Yoruba fi ẹsin abalaye silẹ, ti wọn si tẹwọgba ẹsin Kristiẹni ati ti Musulumi.
Ẹtahoro ọmọ Yoruba lo ku to n gbe awọn orisa abalaye ga, ti wọn si n se ẹsin ibilẹ.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
Idi si ree to se jẹ ohun iyalẹnu lati ri obinrin oyinbo to n kara mọ aasiki ẹsin ibilẹ ju awa alawọ dudu gan an lọ.
Orukọ obinrin naa ni Suzzane Wenger, to wa lati ilu oyinbo, ti kii si fi ọkankan ninu awọn orisa ilẹ Yoruba sere.
Gẹgẹ bi oju opo Wikipedia to wa lori itakun agbaye ti slaye, ipa kekere kọ ni Suzzane Wenger, ti ọpọ mọ si Adunni Olorisa ko, lati ri pe ẹsin abalaye wa ko parun nilẹ Yoruba.
Adunni Olorisa jẹ agbẹgilere, to si maa n fi igi da ara to ba wu, eyi to mu ko rọrun fun lati gbẹ ere nipa oniruuru orisa to wa nilẹ Yoruba.
Bi itan aye obinrin naa si se lọ ree ati ipa manigbagbe to ko nidi agbega asa ati orisa ilẹ Kaarọ Oojire
Ta ni Suzzanne Wenger?
Ọjọ Kẹrin, osu keje, ọdun 1915 ni wọn bi Suzzanne Wenger sile aye, lasiko ogun agbaye akọkọ.
Ilu Graz, lorilẹ-ede Guusu Austria si ni wọn bi obinrin naa si, sinu idile ẹlẹsin Kristẹni, amọ, o nifẹ gbogbo ohun to ba jẹ ti isẹda tabi adayeba.
Eyi lo mu ki Suzzanne lọ kọ nipa isẹ ọna, paapaa ba se n gbẹ igi ni ere, to si lọ yika awọn ilu nla nla lati mọ nipa isẹ naa, to si tun n ta awọn ọja to ba fi igi se.
- Àwọn alálẹ̀ kò ní forí jìn mí tí ń kò bá ṣe ọdún Ṣàngó - Alaafin
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
Nitori ifẹ si isẹ ọna to ni, lara awọn ilẹ to ti sisẹ ọna naa ni Vienna, Italy, Switzerland ati Paris, lorilẹ-ede Faranse.
Ilu Paris si ni Suzzanne wa, to fi se alabapade ọkọ rẹ akọkọ, Ulli Beier ẹni to sẹsẹ ri isẹ olukọ lọgba fasiti Ibadan.
Ulli Bier ati Suzzanne Wenger se igbeyawo nilu London lọdun 1949, eyi to mu ko rọrun fun wọn lati dijọ wa silẹ Naijiria bii tọkọ taya.
Nigba to di ọdun 1950, awọn tọkọ-taya yii lọ tẹdo silu Ede nitori wọn n wa ayika to kun fun ohun isẹda lati maa gbe.
Bawo ni Suzzanne Wenger se gba ẹsin iṣẹṣe?
Suzzanne Wenger ko saadede tẹwọ gba orisa ibilẹ amọ aisan nla kan lo deede gbe e ṣanlẹ laarin ọdun kan ti oun ati ọkọ rẹ wọ Naijiria, ti wọn si tẹdo si ilu Ibadan.
Lọ́dun 1950 yii ni arun ikọ ife da a wolẹ, bẹẹ ni ko si dokita oyinbo kankan larọwọto lati se itọju rẹ, to si n ku lọ bi ọjọ ti n gori ọjọ.
Asiko yii ni awọn olorisa dide, ti wọn si n se itọju obinrin yii pẹlu agbo, egboogi, ewe ati egbo titi ti ara rẹ fi da, to si bọ lọwọ arun asekupani naa.
Lati igba naa, ni Suzzanne ti fi aye rẹ fun awọn orisa, ti ko si boju wẹyin mọ, bẹẹ lo si mu ẹsin bibọ orisa ni ọkunkundun, to si gba a gbọ titi di ọjọ iku rẹ.
Asiko yii si lo salabapade orisa Obatala ati Alagemo, to si nifẹ pupọ si ọna ti wọn n gba bọ awọn orisa yii ati gbogbo ohun to jẹ mọ.
Bi o tilẹ jẹ pe Suzzanne ko gbọ ede Yoruba, sibẹ eyi ko se idiwọ fun un lati maa kọ nipa ilana irubọ ati etutu awọn orisa yii, to si di ọrẹ awọn olorisa naa.
Suzzanne yi orukọ rẹ pada kuro ni ti oyinbo, awọn olorisa si sọ ọ ni orukọ abisọ nilana ẹsin abalaye.
Orukọ rẹ tuntun ni Iwinfunmi Adunni Olorisa, Ọba Samuel Adeleye Adenle, Ataoja tilu Osogbo si lo fun un ni orukọ naa.
Bi Adunni se di iyawo orisa titi di ọjọ ogbo:
Adunni ati ọkọ rẹ tun lọ silu Osogbo lati tẹdo si, ibẹ si ni wọn ti tuka gẹgẹ bi tọkọ-taya.
Obinrin oyinbo naa n tẹsiwaju pẹlu orisa bibọ, to si n kọ ẹkọ lojoojumọ nipa ilana ẹsin abalaye.
Adunni tun dan igbeyawo wo lẹẹkan si, to si tun se igbeyawo pẹlu ọkọ keji, tii se onilu ibilẹ lọdun 1959.
Orukọ onilu naa ni Oloye Ayansola Oniru Alarape, toun naa ti di oloogbe bayii.
Amọ igbeyawo naa ko tun tọjọ, ti wọn fi tuka, ti Adunni si da wa titi opin aye rẹ lai sopo fẹ ọkọ kankan mọ, amọ to fi awọn orisa se ọkọ.
Adunni ko tẹwọ gba orisa kan soso ni pato amọ o gba ilana ẹsin ibilẹ, gbogbo ọna si lo n gba gbe awọn ẹsin abalaye yii larugẹ.
Oniruuru ere ni Adunni fi igi gbẹ lati safihan awọn orisa ilẹ Yoruba, to si n fi owo, ara ati isẹ ọwọ gbe oẹsin abalaye tilẹ Yoruba larugẹ.
Gbogbo awọn ẹlẹsin Kristiẹni ati ti Musulumi lo n se ariwisi si obinrin oyinbo yii pe se lo tun n se agbende ati agbega iwa ibọrisa, eyi to ti n lọ sokun igbagbe.
Amọ, gbogbo ariwisi wọn ni ko tu irun kankan lara Adunni, to si n tẹsiwaju lati maa fọn rere pe ajọsepọ wa laarin awọn ẹsin mẹtẹẹta, ko si iyatọ.
Awọn ohun meremere ti Adunni Olorisa se nidi agbega osiṣa nigba aye rẹ
- Adunni Olorisa sisẹ takuntakun lati jẹ ki ẹka ajọ isọkan agbaye to wa fun agbega asa UNESCO sọ ojubọ orisa Osun di ibudo ajogunba lagbaye lọdun 2005
- Adunni tun se aayan nidi agbelarugẹ orisa Osun lorilẹ-ede Naijiria titi ti wọn fi kede ojubọ Osun bii ibudo pataki to jẹ apeyawawo ati ohun alumọọni nla ni Naijiria
- Ọmọ mẹẹdogun ni Adunni Olorisa gba tọ nigba aye rẹ, bi o tilẹ jẹ oun gan an ko bimọ kankan saye
- Adunni tun da ẹgbẹ alajẹsẹku silẹ lagbegbe rẹ, fun anfaani awọn eeyan to yii ka, eyi to tun wulo fun un lati fi se itọju awọn ọmọ to gba tọ.
- Adunni se gudugudu meje ati ya ya mẹfa lati ri daju pe ojubọ Osun Osogbo dun un wo, to si gbẹ oniruuru ere lati fi se ojubọ naa ni ọṣọ to rẹwa
- Obinrin yii si lo jẹ ohun iwuri fun awọn onisẹ ọna miran ati ohun amuyangan fawọn olorisa, paapaa ninu osu Kẹwaa, ọdọọdun tawọn ogunlọgọ ero ba wa lati se ọdun Osun Osogbo
- Laarin ọdun 1952 si ọdun 1970, Adunni se agbekalẹ awọn iwe alaworan fun awọn Yoruba, bakan naa lo tun kọ ọpọ iwe ni ede Gẹẹsi ati Yoruba.
- Adunni ko fi igbo igbalẹ sere rara, to si ri daju pe wọn n pa igbo yii mọ fun etutu ati orisa bibọ gẹgẹ bii ibi ọwọ ti wọn ya sọtọ fun irubọ nilana abalaye.
- Adunni kii gba kawọn agbẹ ati awọn Agbegilodo ge igi ninu igbo fun iwulo nnkan miran nitori ifẹ to ni si igi ati isẹ ọna
- Bakan naa ni ko fara mọ asa sisọ ayika di asalẹ tabi biba ayika jẹ nipa gige awọn igi to n mu ki ayika rẹwa
- Adunni tun jẹ akọsẹmọsẹ ati akikanju ninu sise asọ adirẹ, to si jẹ ẹni to kọ ọpọ obinrin to n se asọ adirẹ ni ọna ti wọn le gba se asọ na nilana ti igbalode.
- Obinrin oyinbo yii si lo kọ wọn ba se n po kẹmika pọ lati fi se aro fun adire sise, to si tun se agbekalẹ asọ Batik, tii se adirẹ igbalode
- Adunni tun maa n lo aró oni kẹmika yii lati fi se aro fun aworan yiya, eyi to n mu owo wọle ati ipese isẹ oojọ
- Adunni, pẹlu iranwọ awọn olorisa yoku, tun da ọpọ ojubọ orisa to ti poora pada, ọpọ wọn ni wọn ko lo mọ tẹlẹ amọ ti obinrin naa sọ wọn ji pada.
Akoko ikẹyin Adunni Olorisa titi to fi jade laye:
Aadọta ọdun gbako ni Adunni Olorisa lo pẹlu iran Yoruba ko to filẹ bora.
Ọjọ ni ọjọ Aje, ọjọ kejila, osu Kinni, ọdun 2009, ti Aduuni Olorisa dakẹ, to si ki aye pe o digbose se nile iwosan Aguda ti Fatimah to wa nilu Osogbo.
Gbogbo ọmọ mẹẹdogun ti obinrin oyinbo tọ yii si gba tọ ọ lo wa ni ẹba ibusun rẹ lasiko to mi kanlẹ.
Lara awọn ọmọ ti Adunni gba tọ ni Yinka Davies Okundaye ti ọpọ eeyan mọ si Nikky Afirikana, ẹni toun naa gbajumọ nidi isẹ ọna ati asọ Adire sise.
Ọmọ ọdun mẹfa ni Yinka wa nigba to di ọmọ orukan, ti Adunni si gba lati ma a tọju rẹ gẹgẹ bii ọmọ bibi inu rẹ.
Ko si to jade laye ni Adunni ti fi ọrọ silẹ pe wọn ko gbọdọ gbe oku oun sinu yinyin ni ibudo igbokusi tabi se inawo alarinrin lati se oku oun.
Ọpọ eeyan to si gbọ nipa iku akikanju obinrin iya olorisa yii lo ni kii se pe o ku, o sun ni lati di ọkan lara orisa ti iran Yoruba ko ni le gbagbe laelae.
Bakan naa ni awọn ọmọ rẹ fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn sin Adunni nilana ẹsin isẹse amọ ko si ẹni to ge ẹya ara rẹ kankan, lodi si ahesọ ọrọ tawọn kan n sọ kiri.
Ẹkọ ti itan aye Suzzanne Wenger, Adunni Olorisa kọ wa:
Adunni Olorisa ti waye, o si ti lọ mọ ipa manigbagbe to ko nidi agbega asa ilẹ Yoruba ko le parẹ laelae.
Lara awọn ẹkọ naa ni pe ko yẹ ka maa fi ọwọ rọ oun adayeba wa sẹyin nitori ọmọ ale nii fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ.
Bakan naa ni itan igbe aye Adunni kọ wa pe ka maa se anu nipa gbigbe ori awọn ọmọde sori soke boya ọba oke fun wa ni ọmọ abi bẹẹ kọ.
Itan yii tun kọ wa pe ka maa se amulo awọn ohun isẹse wa bii egboogi, agbo, ewe ati egbo nitori iwulo tiwọn naa wa, eyi to ti n lọ sokun igbagbe bayii.