You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wà á kí mi kú oríire lẹ́yìn ìbò, Makinde fi ohùn ránṣẹ́ sí Adelabu
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti fi ọrọ lede wi pe ewe olubori ti oun yoo ja ninu eto idibo si ipo Gomina ti yoo waye loṣu kẹta ọdun yii yoo kọja afẹnusọ, ati pe awọn ẹgbẹ oṣelu alatako gan an yoo ki oun ku oriire.
Makinde sọ ọrọ yii nibi itakurọsọ laarin awọn oludije si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ, eleyii ti ileeṣẹ redio Fresh 105.9 FM ṣe agbekalẹ rẹ.
O ni pẹlu ifẹ ati atilẹyin ti oun n ri lati ọwọ awọn eeyan ilu ati ẹgbẹ oṣelu PDP, ko si ohunkohun ti o le di oun ọlọwọ lati ma wọle fun saa 'keji.
Ninu ọrọ ti o sọ fun ọkan lara awọn oludije ti o n baa ta kangbọn labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, iyẹn Oloye Adebayọ Adelabu nibi itakurọsọ naa; Makinde ni, "Mo ni ero rere si Adelabu, ṣugbọn emi ni maa bori".
O tẹsiwaju wi pe oun ti da ẹrin pa ẹkẹ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ pẹlu bi ipenija ṣe wa lori ipese awọn ohun alumọni, nipa ipese iṣẹ ati sisan owo oṣu lasiko.
O ni iṣakoso oun ti ṣe agbekalẹ awọn ibudo itọju ilera alabọde bii igbalelaadọta jakejado awọn wọọdu to n bẹ ni ipinlẹ naa, gẹgẹ bi o ṣe fi kun ọrọ rẹ pe awọn iṣẹ takuntakun ti oun ti ṣe ni oniruuru ọna laarin ọdun mẹta o le, ni yoo ṣe atiwaye bi oun yoo ṣe tun pada wọle lẹẹkeji.
Makinde gbosuba kare fun awọn eeyan ipinlẹ naa fun atilẹyin ti wọn ṣe fun ijọba rẹ lati ibẹrẹ, gẹgẹ bi o ṣe n rọ wọn lati tẹsiwaju.
O ni iṣejoba kii ṣe fun awọn eniyan ti ko mọ bi a ṣe n ṣe akoso, bikoṣe fun awọn eniyan to mọ nnkan ti wọn n ṣe.
Makinde ni awọn oloṣelu oni madaru ko ni yi oun lọkan pada lori awọn ifojusun ati eto ti o ni fun awọn eeyan ilu.
Bakan naa ni Makinde ṣe alaye wi pe oun yoo ṣe amulo awọn eto ti Adelabu la kalẹ fun ipinlẹ Ọyọ, ti wọn ba dara ju ti oun lọ.
Oludije ti o yẹ ki o ṣe ikẹta wọn nibi itakurọsọ naa, Sẹnetọ Teslim Folarin ti ẹgbẹ oṣelu APC ko fi ara han nibi ipejọpọ naa.
Ọrọ ti o fi ranṣẹ ni wi pe oun wa nibi eto kan ti ẹgbẹ awọn lẹyin Kristi labẹ asia 'Pentecostal Fellowship of Nigeria (PFN)' ṣe agbekalẹ rẹ.