Èèyàn 44,000 pàdánù ẹ̀mí wọn lápapọ̀; ilé 345,000 ló dàwó nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì ní Turkey

Turkey ti pari akitiyan rẹ lati dola ẹmi awọn to wa labẹ palapala ile to dawo lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riri to waye.

Iṣẹlẹ ilẹ riri to waye ni Turkey ati Syria lọsẹ meji sẹyin lo ti mu ọpọlọpọ ẹmi lo.

Ajọ to n gbogunti iṣẹlẹ pajawiri ni Turkey ni, agbegbge Kahramanmaras ati Hatay nikan ni iṣẹ idola ẹmi yo ti tẹsiwaju.

Botilẹ jẹ wi pe awọn adola ẹmi n ṣiṣẹ takuntakun lati dola ẹmi awọn to ṣeṣe ko wa laaye ṣugbon ireti ti n pin boya wọn o ri ẹnikẹni laaye.

Isͅeͅleͅ ileͅ riri ti sͅekoͅlu si agbegbe Guusu- iwoͅ oorun orileͅede Turkey to si ti mu eͅmi oͅgoͅoͅroͅ eniyan loͅ.

Ileesͅeͅ to n risi oͅroͅ oju oͅjoͅ lorileͅede Ameͅrika ni iye iwoͅn ileͅ riri naa to 7.8 magnitude, ti o si rinleͅ to iwoͅn kilomita meͅtadinlogun o le, ni agbegbe Gaziantep.

O ṣeṣe ki iye awọn to padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ ilẹ riri po si nitori ile igbe to to 345,000 ni Turkey lo dawo ti ọpọlọpọ eeyan dawati lẹyin iṣẹlẹ na.

Yunus Sezer ọga agba ẹka to un risi iṣẹlẹ pajawiri ni gbogbo igbe riko ni isẹ idola ẹmi ti duro.

Yunus fikun pe ogoji ile ni awọn adola ẹmi nṣiṣe nibẹ lọwọlọwọ o ṣi ṣeṣe ki apapọ nomba naa dikun lọjọ aiku.

Akowe ijọba orilẹede Amẹrika Antony Blinken lo ti ṣe abẹwo si Turkey lati fi atilẹyin orilẹde han ,abẹwo to ṣe lo ti yẹ ko waye ṣaaju iṣẹlẹ ilẹ riri na.

Blinken yo riri ajo lo si agbegbge Hatay lati wo bi eto idola ẹmi ṣe nlọ lawọn agbegbe ti iṣẹlẹ ilẹ riri ti waye,ti yo si ṣe ipade pọ pẹlu aarẹ Turkey Recep Erdogan lọjọ ajẹ.