You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akeredolu sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Emfiele, ké sí Buhari láti yanjú ìṣòro àìsí owó naira tuntun
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, SAN, ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari ko jawọ ninu ilana owo naira tuntun to n da wahala silẹ laarin ilu.
Akeredolu tun bu ẹnu atẹ lu gomina banki apapọ Naijiria, CBN, iyẹn Godwin Emefiele fun ilana owo naira tuntun naa.
Gomina Akeredolu lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ.
Ninu atẹjade ọhun lo ti bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Buhari bo ṣe fofin de nina owo ₦500 ati ₦ 1000 atijọ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Buhari ba awọn araalu sọrọ, nibi to ti sọ pe oun ti paṣẹ fun CBN ko ko ₦200 atijọ sita ki awọn araalu ṣi maa na titi di ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Amọ o ni ₦500 ati ₦1000 atijọ kii ṣe owo ti awọn araalu le maa na mọ.
“CBN ti ṣe aṣiṣe lori ilana owo naira tuntun”
Akeredolu ni aṣẹ ti Buhari pa ninu ọrọ rẹ si awọn araalu lori owo tuntun naa ko bojumu.
Atẹjade naa ni “Mo fẹ fi akoko yii bẹ Aarẹ Muhammadu Buhari ko wu iwa baba, ko si fopin si ilana owo naira tuntu to n da wahala silẹ laarin ilu yii.”
“Lai si aniani, gomina CBN, Emefiele ti ṣe aṣiṣe nipa ilana owo naira tuntun naa, Ilana ọhun si ti kuna.”
“Ko si ẹni to sọ pe Aarẹ ko laṣẹ lati ṣe ojuṣe gẹgẹ bi Aarẹ, tabi pe gomina CBN ko lagbara lati paṣẹ lori iṣẹ ti wọn yan an fun, amọ kii ṣe nnkan idnunu lati gbe ilana ti yoo maa ni awọn araalu lara kalẹ.”
Akeredolu sọ siwaju si pe bo tilẹ jẹ pe Aarẹ ati gomina CBN n ṣojuṣe wọn labẹ ofin, ko si ofin to to alaafia ati abo awọn araalu.
“A gbọdọ maa na owo atijọ ati tuntun papọ”
Gẹgẹ bii ohun to sọ, iye owo to wa lode bayii ko kari awọn araalu, ati pe ₦200 ti Buhari ni awọn araalu le maa na tiiti di oṣu Kẹrin ko tun le kari awọn eeyan paapaa, nitori naa Buhari gbọdọ wa nnkan ṣe si ọrọ naa.
O pari ọrọ rẹ pẹlu arọwa si Aarẹ pe ko gba ki awọn araalu ṣi maa na owo naira atijọ ati owo tuntun papọ titi di igba ti nnkna yoo pada bọ sipo fun awọn eeyan ko to fidi ofin owo tuntun ọhun mulẹ.
Lẹyin naa lo ni ko si itiju nibẹ ti eeyan ba tun ero rẹ pa lẹyin ti igbesẹ rẹ akọkọ ba fori ṣọpan.