You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Irọ́ ni! EFCC kò bá N400billion nílé Tinubu'
Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ atawọn iwa ibajẹ miran to n ṣe akoba fun ọr aje lorilẹede Naijiria, EFCC ti ṣe alaye pe awọn ko fi igba kankan lọ si ile oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu, bẹẹ ni awọn ko fi igba kankan ka irinwo biliọnu naira, (N400b) mọ ile tabi ọwọ rẹ.
EFCC fi ọrọ yii sita loju opo ayelujara rẹ ni idahun si iroyin kan to n lọ kaakiri pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa kan kọlu ile Bọla Tinubu ti wọn si ba obitibiti owo naa nibẹ.
Ajọ naa ṣalaye ninu atẹjade naa ti alukoro rẹ, Wilson Uwujaren fọwọ si pe oun ko fi igbakugba ṣe iṣẹ to jọ bẹẹ ati wi pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni iroyin yii.
“A ti kofiri iroyin kan to n kaakiri pe awọn oṣiṣẹ ajọ yii lọ si ile Aṣiwaju Bọla Tinubu, oludije ẹgbẹ oṣelu APC ni idibo aarẹ to n bọ lọna, ti wọn si gba obitibiti owo ti o to irinwo billiọnu naira (N400b).
“Ajọ yii fẹ sọ lasọye pe EFCC ko ṣe ohun to jọ bẹẹ rara. Iroyin ofege leyi, ki araalu kọ eti ọgbin sii.”
Ohun ti awọn iroyin ayelujara kan n sọ ni pe aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun ajọ EFCC lati lo tu ile Tinubu yẹbẹyẹbẹ, ati pe irinwo biliọnu naira ni wọn ba nibẹ ninu aja ilẹ kan ni ile rẹ.