A kò mọ irú èpè tí a lè ṣẹ́ fún awakọ̀ tó pa ẹbí Fatinoye mọ́ ṣùgbọ́n....ẹbi Kehinde àti Bukola Fatinoye

Pẹ̀lú ìbànujẹ́ àti arò ni ẹbi Fatinoye ṣe n sọ̀rs nípa tọkọtayà onínúre Bukola àti Kehinde Fatinoye.

Sẹ ẹ ranti tọkọtaya Fatinoye ni ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Guusu Naijiria ti ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria kede pe awakọ wọn, Lekan ti jẹwọ pe oun lo seku pa wọn.

Lorumọju ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2023 yii léyin eto isinonigbagbọ aisun ọdun tuntun ni iṣẹlẹ iabnujẹ yii waye ninu ile tọkọtaya naa nilu Abeokuta.

Pẹlu ibanujẹ ni awọn eeyan ṣe n sọrọ niap arabinrin Bukola ati arakunrin Kehinde Fatinoye pẹlu ọmọ wọn Ore oluwa ti awọn oniṣẹ ibi ṣekupa nipinlẹ Ogun.

Oṣiṣe banki Naijiri ani ọkọ nigba ti iyawo rẹ jẹ oṣiṣẹ Fasiti olohun ọgbin ni Abeokuta nipinlẹ Ogun.

Ogbeni Akinkunmi Jiboku, Rasheed Fajinmi, Zacheaus Fatinoye, Micheal Fatinoye, Sani Ogundele, ṣapejuwe tọkọtay naa ni oniwa tutu to jẹ ọmọluwabi eniyan.

Awọn miran to tunwa nibi eto isin idagbere to waye fun tokotyaya naa tun ṣapejuwe wọn pe ọmọluwabi ẹda ti awọn eeyan maa mọ riri wọn ni wọn jẹ.

Koda, ọpọ sọ pe awọn ko mọ iru epe ti awọn yoo tun ṣe fun Lekan to jẹ awakọ to ṣeku pa awọn oninure naa tọmọtọmọ.