You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí tí a fi mú 'girlfriend' Lekan, ìyà rẹ̀ àti Lekan náà mọ́ àwọn ọ̀daràn rèé- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun kede pe eniyan marun un lo wa ni ikawọ awọn lori iṣẹlẹ ipaniyan idile kan naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa na, Abimbola Oyeyemi ni iya Lekan ati ọrẹbinrin naa yoo foju wina ofin nitori awọn lo ṣugba Lẹkan lẹyin to hu iwa ọdaran naa tan.
‘’Iya Lekan nigba ti a de ọdọ rẹ kọ jalẹ pe ọmọ ohun ko mọ nkankan nipa iṣẹlẹ iku ọga rẹ ati iyawo rẹ.
‘’Iya Lekan ṣẹ pe Lekan wa ni ṣọọṣi pẹlu ohun ni alẹ ọjọ aisun ọdun tuntun naa.’’
‘’Igba ti ọwọ palaba wọn sẹgi tan ni iya ṣẹṣẹ jẹwọ, ki aṣiri gbogbo wọn to tu.’’
‘’Bakan naa ni ọrẹbinrin Lẹkan wa ni ikawọ wa nitori oun naa ṣatilẹyin fun Lẹkan nigba ti a n wa kiri.’’
‘’Ọrẹbinrin rẹ lo gba ile fun, to ra foonu fun un, to tun fi NIN rẹ ṣe iforukọsilẹ fun.’’
Oun naa lo si tun n ṣọ ile ni ọtun ni osi lati mọ boya awọn ọlọpaa nbọ abi ẹnikẹni n gbiyanju lati wa ṣọ ile ọun.’’
Ileeṣẹ ọlọpaa wa fikun un pe awọn naa yoo fi oju wina ofin nitori wọn da abo bo ẹni ti wọn fi ẹsun apaniyan kan, ti iya naa si tun pa irọ.
Dírẹ́bà ní wọ́n gbà mí fún, àmọ́ iṣẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ ní wọ́n ń fí mí sẹ ní mo ṣe pa wọ́n - Dírẹ́bà àwọn Fatinoye
Dirẹba awọn ẹbi Fatinoye ti wọn fi ẹsun kan pe o ṣekupa gbogbo mọlẹbi naa ni ilu Abeokuta, Lekan Adekanbi ti salaye ni ẹkunrẹrẹ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Lekan ni iṣẹ dirẹba ọkọ ni wọn gba oun fun lati maa wa iyawo ọga oun, amọ wọn bẹrẹ si ni lo ohun bi ọmọ -ọdọ.
O ni gbogbo iṣẹ ile ni oun ma n ṣe, ti oun a gba ilẹ inu ile, fọ ilẹ, ti oun a si ṣe ounjẹ ninu ile.
''Daddy ati Mummy fi ẹtọ mi dun mi, wọn fikun iṣẹ mi, wọn lo mi bi ọmọ-ọdọ, wọn o si fikun owo mi.’’
‘’Gbogbo iṣẹ inu ile ni mo n ba wọn ṣe lati ọdunmọdun ṣẹyin ti wọn si kọ lati ran mi lọwọ.’’
‘’Awọn ọga mi fi ẹtọ mi dun mi fun ọpọlọpọ ọdun nitori iṣẹ dirẹba ni wọn gba mi fun, amọ maa fọ aabọ, nu ilẹ, fun aja ni ounjẹ.
Amọ nigba ti mo bere lọwọ wọn pe ki wọn fikun owo mi, wọn kọ , bakan naa ni wọn kọ lati ran mi lọwọ nipa yiya mi lowo.’’
Iyawo aburo Daddy lo kọkọ ba mi sọrọ wi pe iru iṣẹ wo ni wọn gba mi fun? Ni mo sọ fun wọn pe dirẹba ni.
Iyawo aburọ ọkọ Mummy ni bi wọn ṣe n lo mi ko dara ni ilokulo, ti wọn ko si fi owo kun owo mi.
Lẹyin naa ni mo fi ọrọ naa lọ ẹgbọn kan, to si ni ahun lo n damu awọn ọga mi nitori naa ki n tun ero ara mi pa.
Brọda naa gba mi ni imọran lati wa ibọn, amọ mi o tete ri ibọn gba, ẹnikan tilẹ gba 40,000 lọwọ mi lai ṣe nkankan.
Bi mo se de ọdọ Koffi ati ekeji rẹ niyẹn ti wọn tẹle mi lọ ṣe iṣẹ ibi naa ni oru Ọjọ Kini, Oṣu Kini, ọdun 2023.
''Emi kọ, Koffi lo dunbuu Daddy ati Mummy, to fi ọbẹ ge wọn lọrun''
Lekan ni lẹyin ti ohun fun wọn ni account oun ki wọn fi owo si, ti Daddy si fi miliọnu kan naira si ni Koffi le wọn jade.
Lẹkan ni Koffi lo ni ọwọ maa tẹ oun pẹlu account ti oun gba owo si, to si ni ki oun jade sita.
Lẹyin ti ẹmi ati Ahmed ti wọn n pe ni Akamo jade nitori Koffi le wa jade ni a wa nita pẹlu Mummy.
Nigba ti a maa fi wọle pada, Koffi ti dunbu Baba, ti mo si ri ẹjẹ nilẹ, mo pàriwo amọ kete ni Koffi fo mọ iyawo, to si gun un ni ọbẹ lọrun, to si tun rẹ ọfun rẹ.
Lẹyin naa lo ni ki a maa lọ, amọ awọn ọmọ wọlẹ, ti a si lọ ju wọn sinu omi.
Bi a ṣe n lọ naa ni Koffi n sọ pe oun ti ṣe aṣiṣe nitori oun ko pa awọn ọmọ mejeeji naa.
Ọjọ Kẹsan an, osu Keji, ọdun 2023 ni ọwọ tẹ awọn ọdaran naa, ti wọn si ti wa ni ọgba ẹwọn bayii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣetan lati gbe wọn lọ si ileẹjọ lati koju ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.
Ta ni tọkọ-tiyawo Fatinoye ti wọn ṣekupa?
Iwadii fihan pe oṣiṣẹ banki apapọ orileede Naijiria, CBN tẹlẹri ni Ọgbẹni Kẹhinde Fatinloye, nigba ti iyawo rẹ, Arabinrin Bukọla jẹ oṣiṣẹ fasiti ọgbin to wa niluu Abẹokuta, iyẹn Federal University of Agriculture, Abẹokuta, FUNAAB.
Lara awọn ti wọn n gbe lagbegbe naa lo pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana nigba ti wọn ri ile wọn to n jona lọwọ, ti wọn si ni k’awọn panapana to debẹ, aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ.
Igba ti wọn lawọn panapana wọnu ile naa, ni wọn too mọ pe n ṣe ni wọn wa dana sun t’ọkọ ti’iyawo naa mọle.