You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn nǹkan mẹ́wàá nípa olùdíje sípò gómìnà Ekiti lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party
Olugbenga Daramola Rowland jẹ ògbóǹtarìgì olóṣèlú ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pàápàá ní ìpínlẹ̀ Ekiti.
O sì ń díje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti níbi ìdìbò tí yóò wáyé ní ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022.
Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Olugbenga ń díje dupò gómínà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, LP.
Ọmọ bíbí ìlú Ise Ekiti ní ìpínlẹ̀ Ekiti ni Olugbenga, ibẹ̀ sì ni wọ́n bi sí pẹ̀lú.
Ise Ekiti àti Akure tíì ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo ni Olugbenga gbé dàgbà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé BBC kò le sọ ìgbà kan pàtó tí wọ́n bí Olugbenga ohun tó wà ní ojú òpó Facebooko rẹ̀ fi hàn pé ní ọdún 2022 ni yóò pé ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta.
Ilé ẹ̀kọ́ Ekiti Parapo College, Ido Ekiti ni ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde.
Kí Olugbenga tó di olùdíje sípò gómìnà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, òun ni akọ̀wé owó àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà láti ọdún 2020.
Iṣẹ́ àdáni ni Olugbenga ń ṣe.
Ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ́n oṣù Kìíní, ọdún 2022 ni ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party panupọ̀ láti gbé àsíá ẹgbẹ́ náà lé Olugbenga lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò máa kojú àwọn olùdíje láti ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn.
Nígbà tí alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Odunayo Okunade gbé àsíá ẹgbẹ́ lé Olugbenga lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùdíje ẹgbẹ́ náà, Olugbenga ní àsìkò ti tó láti gba ìpÍnlẹ̀ Ekiti là lọ́wọ́ àwọn àjòjì.
Bákan náà ló jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti àti láti le ri pé ìpínlẹ̀ Ekiti rí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú tó nílò ní ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin Labour Party.
Onile Ibrahim Yusuf, ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ni òun àti Olugbenga dijọ ń gbé àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party níbi ìdìbò ọjọ́ Àbámẹ́ta.