Sáájú ìdìbò 2023, Obasanjo, Wike , Obi, Makinde ṣèpàdé ní London

Oríṣun àwòrán, BBC HAUSA
Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oluṣẹgun Obasanjo ti sẹpade pẹlu oludije lẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi ati gomina ipinlẹ Rivers. Nyesom Wike ni ilu London.
Bio tilẹ jẹpe ko han si awọn eniyan ohun ti wọn jọ jiroro, iroyin ni o ṣeeṣe ko jẹ nipa idibo sipo aarẹ ti ọdun 2023 lorilẹede Naijiria.
Gomina Wike wa ni ibi ipade naa pẹlu gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ati gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom.
Awọn miran to wa nibi ipade naa ni gomina ipinlẹ Abia, Okezie Ikpeazu ati gomina ipinlẹ Crooss River, Donald duke ati awọn miran.
A n gbiyanju lati fa Wike mọra - Tinubu
Ipade naa waye lai tii pe wakati mẹrinlelogun ti Wike ṣepade pẹlu oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ni London.
Oṣiṣẹ timọtimọ oludije sipo aarẹ naa lo sọ fun BBC Hausa pe gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ati awọn gomina miran jiroro pẹlu Bola Tinubu
Awọn ti wọn wa pẹlu gomina Wike ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ati gomina ipinlẹ Abia, Ikpeazu Okezie.
Iwadii fihan pe awọn gomina naa kuro lorilẹede Naijiria lọ si UK lasiko ti aigboraẹniye n ṣẹlẹ lẹgbẹ oṣelu PDP.
Alhaji Ibrahim Masara to fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC ni ipade naa da lori ati bori ni idibo sipo aarẹ ti yoo waye ni ọdun 2023.
Masari ni igbagbọ awọn nipe awọn gomina ti wọn ba ṣe ipade naa yoo dibo fun wọn ni idibo to n bo
Se lootọ ni Wike ati Atiku yoo ṣepade ni London?
Amọ Masari fikun un pe eleyii ko niiṣe pẹlu boya Wike yoo kuro ni ẹgbẹ oṣelu PDP lati ṣiṣẹ fun wọn ni ọdun 2023.
O ni ko pọndandan ko duro ni ẹgbẹ oṣelu rẹ amọ nitori jẹ alagbara laarin awọn gomina, o di dandan ki awọn ṣiṣẹ pẹlu rẹ lati le bori.
Iroyin miran fikun un pe oṣeeṣe ki Wike ṣepade pẹlu Atiku ni ilu London lọna ati wa opin si aawọ to wa ni aarin wọn.
Aawọ naa ko ṣẹyin bi oludije lẹgbẹ PDP naa ṣe yan gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa gẹgẹ bi igbakeji oludije sipo aarẹ, lẹyin ti Wike kuna lati bori ninu idibo abẹlẹ to waye lẹgbẹ oṣelu naa.












