You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé rèé nípa àìsàn tó ń ṣe mi, n kò rí ìrànwọ́ gbà lọ́dọ́ àwọn òṣèré tíátà - Fadeyi Oloro
Gbajugbaja oṣere tiata, Oloye Ayo Arowosafe, ti ọpọ mọ si Fedeyi Oloro, ti rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ Naijiria lati gba ẹmi rẹ la lọwọ aisan to n se e.
Gẹgẹ bi Fadeyi Oloro se wi, aisan ikọ Ife, ti oloyinbo mọ si Tuberculosis, lo ni o n ba oun finra.
Fadeyi, lo sadede di awati ninu ere agbelewo, to si kuro nidi isẹ oojọ rẹ naa nitori aisan to n ba ja lati bii ọdun diẹ sẹyin.
Agba osere tiata naa si ti ta ọpọlọpọ awọn dukia rẹ, lati sa owo jọ fi ṣe itọju ara rẹ.
Ninu afọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Alaroye, Fadeyi Oloro ni oun si ni igbagbọ pe oun yoo bori aisan naa, ti oun yoo si tun pada sidi ere sinima laipẹ.
"Nigba ti aisan yii de, n ko mọ nnkan to sẹlẹ, o kan dede ki mi ni"
Fadeyi Oloro, ẹni to n mi gunle-gunle lati sọrọ sita ninu fidio naa, lo foju han pe o nira fun-un lati sọrọ ja soke.
O tẹsiwaju pe “Nigba ti aisan buruku naa de, n ko mọ nnkan to sẹlẹ, o kan dede ki mi ni, mo dẹ sare si, mo wo gbogbo agọ ara mi sugbọn gbogbo rẹ lo ye Ọlọrun.
“Mo ti kọ ọpọ awọn itan silẹ lati fi ṣe sinima sugbọn n ko le ṣe.
“Kekere ni ẹ pe aisan yii ni, to fi di pe wọn bẹrẹ si ni ma ta dukia lemi lori sugbọn gbogbo rẹ lo yẹ Ọlọrun.
"Ẹ ran mi lọwọ, ẹ ma jẹ ki n ku bayii"
Agba oṣere tiata, to tun jẹ ilumọka naa, ti wa ke sita pe ki awọn eeyan ilu ran oun lọwọ lori aisan.
O ni o ṣe ni laanu pe gbogbo erongba oun ni ko le wa si imusẹ nitori oun ti kọ awọn itan sinima silẹ pe Fadeyi ko gbọdọ ku bayi.
“Ẹyin eeyan, ẹ wa dide iranlọwọ fun mi nipa ti owo, nipa ti iranlọwọ.
“Ẹ jọwọ, ẹ ma jẹ ki lọ bayi. A ri ẹni ti iru tiẹ ko to bayi, to ti jade laye, n ko fi yọ wọn mo fi n gbe orukọ Ọlọrun ga ni.
“Mo mọ iye osu ti mo fi ti wa ni idubulẹ aisan bayi.
“Owo ti mo ti na ti n lọ ọpọ milọnu naira bayi, ti mo si ti fi gbogbo iyoku sọwọ Ọlọrun.
"N ko ti i ri iranlọwọ lati ọdọ onitiata kankan"
Arowosafe tẹsiwaju pe ẹni ti Ọlọrun ba ran si eeyan ni yoo ṣeni laanu ati pe oun ko ti ri iranlọwọ kan gba lati ọdọ awọn akẹgbẹ rẹ nidi isẹ tiata.
O ni oun si ni igbagbọ pe awọn akẹgbẹ oun lagbo tiata yoo dide iranlọwọ fun oun laipẹ lati bori aisan naa.
“Ko ti si oni tiata to wa ba mi lati ran mi lọwọ ninu aisan yii sugbọn mo mọ pe wọn ma wa. Ko ye wọn ni.
“Ti iru kan bayi ba sẹlẹ, o yẹ ka dide iranlọwọ fun ara wa ni. O le ma deba owo lọwọ ẹlomii.
“Iranlọwọ awọn ololufẹ mi ni mo fẹ, ko si nkankan mọ, o ti pẹ ti mo de ile-wosan nitori pe ko si owo. Ile wosan to yẹ ki ma lọ ni ọsẹsẹ."