Ọba Charles á yan Ọmọọbabìnrin Anne àti Ọmọọbakùnrin Edward gẹ́gẹ́ bíi Aṣojú Ọba

Ọba Charles kẹta ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣe afikun awọn mọlẹbi orí ade ti yoo maa ṣe amulelọwọ fun Ọba ni bi awọn ọrọ to ba jẹ mọ aafin - to si ti fa Ọmọọbabìnrin Anne ati Ọmọọbakùnrin Edward kalẹ.

Lọwọ lọwọ, awọn igbimọ Ọba ni, Olori Camila ati awọn mẹrin miran.

Ti awọn meji lara wọn to jẹ Ọmọọbakùnrin Andrew ati Harry ko ki n ṣe osisẹ aafin mọ.

Ọjọ Aje, ni wọn ti ka ibeere Ọba Charles kẹta si eti awọn ọmọ ile igbimọ.

Igbagbọ ni pe awọn ọmọ ile yoo fesi laipé, ti yoo si jẹ ọjọ ti ìjọba yoo gbe aba lọ si ile ìgbimọ asofin, eyi ti yoo fun Ọba ni anfani lati kede afikun meji si awọn osisẹ aafin.

Igbesẹ yii lo da le igbinyanju awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati yanju aawọ lori ẹni ti yoo ma ṣe amulelọwọ tabi asoju tabi igbakẹji fun Ọba ti o ba rin irinajo, tabi o rẹ ẹ ti ko si ni le ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bii olori ilu.

Ni bayi meji lara awọn igbimọ oniduro ọhun ni wọn ko ni anfani lati ṣe amulelọwọ tabi aṣoju,

Ọmọọba Andrew yọwọ kuro ninu isẹ aafin lẹyin ibasẹpọ rẹ pẹlu ọmọ orilẹede Amẹrika, Jeffrey Epstein.

Ọmọọba Harry n gbe pẹlu awọn mọlẹbi rẹ, ti oun naa si ti fi ipo silẹ.

Kini iṣẹ awọn Aṣoju Oba to n dile mu?

Ati Ọmọọbabinrin Anne ati Ọmọọbakunrin Edward ni o ti sisẹ tẹlẹ gẹgẹ bii amulelọwọ ki awọn kan to gba a lọwọ wọn.

Isẹ awọn amulelọwọ aṣoju yii ni pe ti Ọba ba rin irinajo tabi o rẹ, wọn le buwọlu iwe, gba alejo, se ipade ati bẹe bẹe lọ.

Igbagbọ wa pe Ọba, Olori, Ọmọọbakunrin ati Ọmọbabinrin ilẹ Wales yoo bẹrẹ irin ajo lọdun to n bọ, eyio to ṣokunfa lilo awọn igbimọ oniduro lati dele de wọn.