Iléẹjọ́ wọ́gilé Akpabio gẹ́gẹ́ bíi olùdíje Sẹ́nétọ̀ ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom 

Ileẹjọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja ti wọgile idajọ ileẹjọ giga lati yọ Godswill Akpabio gẹgẹ bii oludije sipo sẹnẹto labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC fun ariwa ìwọ oorun ipinlẹ Akwa Ibom.

Igbimọ ẹlẹni mẹta tí Adajọ Damlami Senchi saaju rẹ lọjọ Aje, ni Akpabio kuna lati pese awọn ẹri lasiko to yẹ.

Igbimọ ọhun tẹsiwaju pe Akpabio, ẹni to ra tikẹẹti lati dupo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ko kopa ninu eto abẹnu to waye ni ọjọ kẹtadinlọgbon, oṣu karun-un.

Tí ajọ eleto ìdibo INEC, to ṣe agbatẹru ìdibo si kede Udom Ekpoudom gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ naa.

Kini ilé ẹjọ́ kọ́kọ́ sọ lórí ọ̀rọ̀ náà?

Saaju ọjọ kejidinlelogun ni ileẹjọ giga niluu Abuja palasẹ fun ajọ INEC pe ko kede Sẹnẹto Akpabio gẹgẹ bii oludije ti ẹgbẹ faa kalẹ fun ìdibo abele to waye ni ọjọ kẹsàn-án oṣu kẹfa.

Bakan naa ni ileẹjọ giga ọhun palasẹ fun ajọ INEC pe ko gbe orúkọ Akpabio síta gẹgẹ bii oludije sẹnẹto to n soju ariwa ìwọ oorun ipinlẹ Akwa Ibom saaju eto idibo lọdun 2023.

Ileẹjọ ni igbesẹ Kọmisonna ajọ ọhun lati ma kede Gomina tẹlẹ, gẹgẹ bii oludije sẹnẹto labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni o lodi sì ofin

Adajọ Emeka Nwite to gbe ìgbẹjọ kalẹ ni ọna to ba ofin mu ni ẹgbẹ oṣelu APC gba lati kede Akpabio gẹgẹ bii oludije sẹnẹto to borí ninu eto ìdibo abele ninu oṣu kẹfa.

Adajọ tun wa fi ẹsun kan ajọ INEC wọn lẹdi apopọ mọ ẹgbẹ Augustine Ekanem láti ṣe mọdarun eto ìdibo abele ẹgbẹ oṣelu APC.q