You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Adájọ́ tí Ọlọ́pàá yin ìbọn fún ti jáde láyé
Adajọ, Monica Kivuti ti ile ẹjọ Magistrate lorilẹede Kenya ti Ọga ọlọpaa kan yin ibọn lu lasiko igbẹjọ ti jade laye.
Adajọ Martha K Koome lo lu tufó iroyin naa sita lori ayelujara.
Ninu ọrọ to gbe sori ayelujara X, Adajọ Koome ni Adajọ Monica Kivuti lo jade laye lẹyin to farapa lasiko ti ọlọpaa yinbọn lu.
Lọjọbọ ọsẹ yii ni Ọga agba ni ileeṣẹ ọlọpaa, Kipchirchir Kipruto yinbọn lu adajọ lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ
Ọlọ́pàá yìnbọn lu Adájọ́ lásìkò ìgbẹ́jọ́
Ọga ọlọpaa kan sina bọlẹ fun Adajọ ileẹjọ magistrate ni olu ilu Kenya, Nairobi.
Iṣẹlẹ naa lo jẹ ohun iyalẹnu fun ọpọ araalu lorilẹede naa.
Ohun to tẹ wa lọwọ ni BBC ni pe, Ọga ọlọpaa ti orukọ n jẹ Kipchirchir Kipruto binu nitori ile ẹjọ kọ lati gba baali iyawo rẹ .
Ko pẹ si igba to gbe idajọ kalẹ ni Ọlọpaa yii yinbọn lu Adajọ Monica Kovuti pe ran iyawo rẹ lọ si ẹwọn fun ẹsun ti ile ẹjọ ri pe o jẹ bi.
Ọga ọlọpaa naa to jẹ olori fun ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Londiani ni iwọ oorun orilẹede naa yọ ibọn naa sita lati apo rẹ, to si yin lu Adajọ, ẹni to si farapa.
Kete bi iṣẹlẹ naa waye ni ija bẹ silẹ ni ile ẹjọ, ti ọkan lara awọn ọlọpaa si ṣekupa Kiprutu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni mẹta ninu awọn ọlọpaa to koju Kiprutu lo farapa ninu iṣẹlẹ naa.
Adajọ atawọn mẹta to farapa nibi iṣẹlẹ naa ti wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.