You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
WHO kéde ìlànà tuntun láti kojú ìṣòro àìrí ọmọ bí
Àjọ tó ń rí sí ìlera lágbàáyé, World Health Organization, WHO, fún ìgbà àkọ́kọ́, ti gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ láti kojú àìrí ọmọ bí tó máa ń da ọ̀pọ̀ obìnrin láàmú.
Àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi sójú òpó ayélujára wọn sọ pé obìnrin kan láàárín obìnrin mẹ́fà tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín obìnrin tó lè bímọ ló ń kojú àìrí ọmọ bí.
WHO ní ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí àwọn lọ́kọláya tó bá ń kojú ìṣòro yìí nílò láti ṣe ni lílọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò tó péye.
Àtẹ̀jáde náà sọ pé kìí ṣe obìnrin nìkan ló máa ń kojú ìṣòro yìí bíkòṣe pé àwọn ọkùnrin náà máa ń la ìṣòro kí àtọ̀ wọn má lè fún obìnrin lóyún kọjá.
Wọ́n ní síbẹ̀, àwọn obìnrin ló máa ń kojú ìpèníjà àtàwọn ìnìra tó máa ń ti ẹ̀yìn àìrí ọmọ bí wá.
WHO sọ pé ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn obìnrin tó ń kojú ìṣòro àìrí ọmọ bí ló máa ń kojú ìfìyàjẹni nínú ìgbéyàwó nítorí àìrí ọmọ bí.
Àjọ ètò ìlera àgbáyé náà ní ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ni kò ní àǹfàní sí ilé ìwòsàn fún ètò àyẹ̀wò tó péye láwọn orílẹ̀ èdè kan
Bákan náà ni wọ́n wòye pé àwọn ìnáwó tí àwọn tó bá ń wá ọmọ máa ń ná lórí àyẹ̀wò àti ìtọ́jú máa ń pọ̀ púpọ̀ tó sì jẹ́ pé àpò ara wọn ni wọ́n ti máa ń mu lọ́pọ̀ ìgbà.
"Tí àwọn tọkọtaya bá gbìyànjú láti lo ìlànà IVF, owó rẹ̀ wọn púpọ̀, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ní owó náà."
Èyí ló mu wọn gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ fáwọn tó bá ń wá ọmọ láti jìnà sí àti pé àwọn ìlànà náà kìí ṣe fún obìnrin bíkòṣe àti ọkùnrin náà.
Àwọn ìlànà náà nìyí:
- Tọkọ taya tó bá ń wá ọmọ kò gbọdọ̀ máa fa sìgá, igbó tàbí gbogbo nǹkan tó bá ti nííṣe pẹ̀lú fífa èéfí sínú.
- Tọkọtaya gbọdọ̀ jíná sí ọtí mímu.
- Lílo egbògi olóró jẹ́ ohun tí àwọn tó bá ń wá ọmọ gbọdọ̀ jìnà sí gidigidi yálà ọkùnrin tàbí obìnrin.
- Wọ́n gbọdọ̀ jìnà sí lílo oògùn tí kìí ṣe pé dókìtà ló bá kọ ọ́ fún wọn.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ náà ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ló le ṣokùnfà àìrí ọmọ bí fún àwọn obìnrin, tí wọ́n sì ní ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àyíká náà wà lára ohun tó le ṣòkùnfà àìrí ọmọ bí fáwọn ọkùnrin.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn oúnjẹ kan wà tó le ṣe ìrànwọ́ nípa kí ọlẹ̀ ọmọ tètè sọ nínú obìnrin, tí wọ́n sì gba àwọn obìnrin tó bá ń wá ọmọ nímọ̀ràn láti máa jẹ àwọn oúnjẹ náà lóòrèkóòrè.