Gbogbo ẹni tó bá ní ẹ̀rí wípé mo fi owó ra ìbò kó mú wá – Oyebanji

Gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ipínlẹ̀ Ekiti, Abiodun Oyebanji ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti fún bí wọ́n ṣe jáde láti dìbò yan òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò máa tukọ̀ ìpínlẹ̀ náà fún mẹ́rin.

Oyebanji nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ wí pé òun gba èsì ìdìbò ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 níbi àjọ INEC ti kéde rẹ̀ wípé òun ló gbégbá orókè wọlé.

Oyebanji rọ gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú òun nígbà tí wọ́n bá búra wọlé fún òun nínú oṣù Kẹwàá.

Ó ní ó pọn dandan kí gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti kí wọ́n fi ohùn ṣọ̀kan kí ìdàgbàsókè, àláfíà àti ìtẹ̀síwájú le bá ìpínlẹ̀ Ekiti.

Bákan náà ló fi kun pé gbogbo àwọn iṣẹ́ ribiribi tí ìjọba tó wà ní orí àléfà tí òun ń gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ gúnlè ní òun yóò tẹ̀síwájú lé lórí.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní gbogbo ìlérí tí òun ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ni òun yóò ṣe àmúṣẹ, tó sì rọ àwọn ènìyàn láti kún ìjọba òun lọ́wọ́.

Oyebanji ni gbogbo àwọn tí àwọn jọ díje dupò ni òun yóò kàn sí lójúnà àti mu nínú omi ìmọ̀ wọn kí ìpínlẹ̀ Ekiti le ní ìlọsíwájú tó yẹ.

Ó ní òun àti àwọn ará ìlú ni àwọn yóò jọ ṣe ìjọba nítorí gbayawu ni ilẹ̀kùn òun yóò wà ní ṣíṣí kalẹ̀ fún wọn nítorí à ti mọ òun tí wọ́n bá ń fẹ́.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án àti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party, APC wí pé owó ni wọ́n fi ra ìbò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, Oyebanji ní ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀rí níbi tí òun bá ti ń fún ènìyàn lówó kó mu jáde.

Ó ní òfin fi àyè gba gbogbo ẹni tó bá fẹ̀sùn kan ènìyàn láti fi ẹ̀rí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nítorí náà ni òun ṣe ń pe àwọn tó ;n gbé ìròyìn náà kiri níjà láti fi ẹ̀rí gbe ọ̀rọ̀ wọn lẹ́sẹ̀.

Abiodun Oyebanji ti APC mókè nínú ìbò gómìnà l‘Ekiti

Olùdíje ẹgbẹ́ APC fẹ̀yìn alátakò rẹ̀ nínú PDP àti SDP janlẹ̀ nínú ìbò gómìnà Ekiti

Ẹgbẹ oṣelu APC ti jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ekiti lọjọ Abamẹta.

Ṣaaju ni ẹni to n ṣoju fun ajọ eleto idibo, INEC, to se akojọpọ ati kokari esi ibo naa, Ọjọgbọn Kayode Oyebode Adebowale ti kọkọ n ka ibo naa.

Gbagede ọọfisi INEC to wa lagbegbe New Iyin Road, niluu Ado Ekiti, ni isẹlẹ naa ti waye lalẹ ọjọ Abamẹta si afẹmọju ọjọ Aiku.

Oludjije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Biodun Oyebanji lo gbegba oroke ninu eto idibo naa.

Nigba ti oludije ninu ẹgbẹ oṣelu SDP, Segun Oni n sare tete tẹle lẹyin lati se ipo keji, ti Bisi Kolawole ti ẹgbẹ oṣelu PDP si ṣe ipo kẹta ninu eto idibo ọhun.

Iye apapọ ibo ti APC ni ni: 187,057

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni apapọ ibo: 67,457

Nigba ti ẹgbẹ oṣelu SDP ni ibo: 82,211

Bi ibo ijọba ibilẹ kọọkan se lọ ree:

Ijọba ibilẹ Ijero:

Apapọ iye eeyan to fi orukọ silẹ 65,328 Apapọ iye oludibo 25103 A 08 ADC 96 ADP 201 APC 13754 LP 16 NNPP 48 NRN 17 PDP 4897 PRP 87 SDP 5006 YPP 59 ZLP 18

Èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Emure rèé

Iye eeyan to dibo: 14,509

Esi ibo:

A 4

AAC 15

ADC 81

ADP 92

APC 7728

APGA 14

APN 16

APP 70

LP13

NNPP 13

NRN 19

PDP 2610

PRP 24

SDP 3446

YPP 45

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti southwest

Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:53,713

Iye eeyan to dibo:19,982

A 3

AAC 22

ADC 100

ADP 195

APC 9679

APGA ASK

APN 10

APP 170

LP 14

NNPP 30

NRN 33

PDP 4474

PRP 43

SDP 4577

YPP 41

ZLP 26

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ikere Ekiti

Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:65, 661

Iye awọn to dibo: 24109

A 16

AAC 49

ADC 3764

ADP 310

APC 12086

APGA 25

APN 17

APP 49

LP 14

NNPP 47

NRM 10

PDP 3789

PRP 35

SDP 1943

YPP 38

ZLP 9

Wo èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ileje meje níbí

Iye awọn to forukọsilẹ lati dibo:18,791

Iye awọn to dibo: 8,439

A 04

AAC 09

ADC 216

ADP 47

APC 4357

APGA 04

APM 05

APP 41

LP 01

NNPP 06

NRM 06

PDP 1157

PRP 18

SDP 2344

YPP 04

ZLP 04

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Moba

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 53,257

Iye èèyàn tó dìbò: 20,743

A 13 AAC 20 ADC 75 APC 11609 Apga 11 APM 11 APP 41 LP 06 NNPP 09 NRM 05 PDP 3530 PRP 41 SDP 4904 ZLP 08

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Efon

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 30,076

Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 11,046

A 02

AAC 04

ADC 17

ADP 77

APC 4012

APGA 11

APM 05

APP 11

LP 09

NNPP 04

NRM 16

PDP 6303

PRP 20

SDP 339

YPP 07

ZLP 02

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti West

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 59,220

Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 23,750

A 09

AAC 26

ADC 90

ADP 178

APC 15322

APGA 30

APM 15

APP 105

LP 5

NNPP 28

NRM 29

PDP 3386

PRP 34

SDP 3863

YPP 24

ZLP 24

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun Ifelodun

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 70,467

Iye èèyàn tó dìbò: 24,123

A 5

AAC 33

ADC 141

ADP 191

APC 13125

APGA 16

APM 20

APP 112

LP 9

NNPP 29

NRM 20

PDP 4712

PRP 33

SDP 5010

YPP 44

ZLP 15

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Oye

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 65,170

Iye èèyàn tó dìbò: 24,925

A 14

AAC 34

ADC 83

ADP 210

APC 13396

APGA 17

APM 29

APP 167

LP 12

NNPP 33

NRM 23

PDP 4122

PRP 84

SDP 5391

YPP 32

ZLP 19

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ido/Osi

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 57,780

Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 23,848

A 05

AAC 20

ADC 88

ADP 155

APC 10321

APGA 20

APM 11

APP 107

LP 10

NNPP 52

NRM 31

PDP 2871

PRP 72

SDP 9489

YPP 32

ZLP 21

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ise oorun

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 46,712

Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 17,534

A 04

AAC 14

ADC 82

ADP 145

APC 8074

APGA 22

APM 18

APP 126

LP

NNPP 07

NRM 15

PDP 2588

PRP 60

SDP 5909

YPP 38

ZLP 19

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ado

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 179,088

Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 50,592

A 49

AAC 67

ADC 415

ADP 728

APC 23831

APGA 70

APM 62

APP 448

LP 47

NNPP 83

NRM 58

PDP 7575

PRP 141

SDP 15214

YPP 125

ZLP 51

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ikole

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 71,690

Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 30,470

A 11

AAC 34

ADC 114

ADP 484

APC 16417

APGA 33

APM 19

APP 148

LP 14

NNPP 37

NRM 20

PDP 6266

PRP 88

SDP 5736

YPP 47

ZLP 13

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Gbonyin

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 53,788

Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 20,308

A 11

AAC 18

ADC 73

ADP 190

APC 11247

APGA 21

APM 19

APP 156

LP 05

NNPP 22

NRM 16

PDP 3947

PRP 41

SDP 4059

YPP 20

ZLP 22

Èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti East

Iye àwọn tó forúkọsílẹ̀ láti dìbò: 61,360

Iye èèyàn tó gba òntẹ̀ láti dìbò: 24,024

A 08

AAC 012

ADC 162

ADP 198

APC 12099

APGA 25

APM 17

APP 147

LP 013

NNPP 30

NRM 29

PDP 5230

PRP 45

SDP 4982

YPP 49

ZLP 19