Ooni Ile Ife, Adeyeye Ogunwusi sọ ìdí tó fi fẹ́ ìyàwó púpọ̀

Ọọni ilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji sọ pe oun ko ṣa dede fẹ iyawo pupọ lati ko obinrin jọ laafin bi awọn ẹni iṣaaju gẹgẹ bi awọn kan ṣe le maa ro.

Ninu ọrọ to sọ nibi eto kan to waye lati fi dupẹ fun awọn oṣiṣẹ afin rẹ, iyẹn ile Oodua, gẹgẹ bi ara ayẹyẹ fun sisami ọdun rẹ lori itẹ ni Ọọni Ogunwusi ti ṣalaye ọrọ yii.

Ọọni ile ifẹ ni kii ṣe lati figagbaga loun tori fẹ awọn iyawo pupọ bi ko ṣe lati tubọ mu ki ogo ilẹ adulawọ goke si.

“Ọlọrun fi awọn iyawo rereti wọn jẹ ọrẹ tootọ ati alabarin rere ta mi lọrẹ. Erdi fifẹ ọpọlọpọ Olori kii ṣe nitori orogun tabi figagbaga bikoṣe lati fi aye silẹ fun igbeleke ogo adulawọ lọna ati lee ṣiṣẹ pupọ sii lọna ati maa ṣe iranwọ to yẹ fun ọmọniyan nipasẹ awọn olori mi ti awọn pẹlu ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin. Akẹkọjade awọn ile ẹkọ giga fasiti ni Naijiria ati loke okun ni wọn.

"Mo ni dokita niyawo, mo ni agbẹjọro niyawo, mo ni onimọ ẹrọ nipa alumọni inu omi ati aṣaṣọ lẹṣọ niyawo, mo ni akẹkọọjade fasiti Cambridge ati Harvard niyawo, mo ni oluṣiro owo to gba iwe aṣẹ nilẹ Gẹẹsi niyawo ati bẹẹbẹ lọ.

"Yatọ si pe awọn Olori mi rẹwa pupọpupọ, ọpọlọ wọn gan ji pepe, wọn kawe doju ami, wọn ri ita, wọn si kọ wọn wọn si tun gbẹkọ. Ki wa lo de ti emi ko ni dupẹ lọwọEledumare?"

Ọọni Ogunwusi atawọn Olori laafin Oodua

Ni oṣu kẹsan an ni Ọọni fẹ akọkọ ninu ohun ti yoo di eto igbeyawo ni ṣisẹ-n-tẹle eyi to ṣi duro lori mẹfa bayii.

Ọpọ lo n woye igbesẹ ti Arole Oodua yoo gbe lẹyin ti Naomi Silẹkunọla kede lori ayelujara loṣu kejila ọdun 2021 pe oun ti fi Ọbalaye naa silẹ.

Amọṣa lọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ọdun 2022 ni ọọni gbe Olori Mariam Ogunwusi niyawo gẹgẹ bii yeyelua tuntun. Lẹyin eyi ni Olori Elizabeth Ọpẹoluwa, olori Tobi, Olori Ashley, Olori Ronkẹ ati Temitọpẹ wọle si aafin Oodua ni ṣisẹ-n-tẹle.

Gbogbo ohun ti mo fẹ da nile aye ni mo ti da -Ọọni

Ọọni Ogunwusi ni gbogbo ohun ti o ku fun oun lati maa ṣe bayii ni lati maa ṣeto iranwọ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ.

“Gbogbo ohun ti mo fẹ da nile aye ni mo ti da bayii. Ohun to ku fun mi ko ju lati maa gbe awọn eeyan ga, ki n si maa ṣe iranwọ to yẹ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ wa ati ṣiṣe iranwọ fun awọn ọdọ ilẹ afirika lati maa dagba sii ni koriya. Eduwa si ti fi awọn obinrin to n gbaruku ti iran mi ti mi. Ki lo de ti n o ni dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba?”