Wo ìdí tí wọ́n fi dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún fún bàbá ẹni ọdún 101 lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tó ṣẹ̀

Josef S

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arakunrin kan to jẹ ẹṣọ alaabo nibudo ogunlende Nazi ti gba idajọ ẹ̀wọ̀n ọdun marun-un, nitori pe o ṣe iranlọwọ ninu pipa ẹgbẹẹgbẹrun ẹlẹwọn ni Sachsenhausen nitosi Berlin.

Josef S to jẹ ọdaran ikọNazi to dagba julọ ninu awọn to jẹjọ ni Germany ti kọkọ parọ pe oun kii ṣe oṣiṣẹ alaabo SS nibudo naa. Wọn lo jẹ bi fifi aaye gba pipa eeyan 3,518.

O tun jẹbi pe o kopa ninu àwọn to yinbọn mọ awọn ẹlẹwọn àjọ Soviet lasiko ogun agbaye keji, to fi mọ fifi afẹfẹ gaasi Zgklon B pa awọn eeyan mi.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún eeyan lo ku ni Sachsenhausen lasiko ogun agbaye keji, nitori ebi, iṣẹ ẹrú, fifi ẹ̀yà ara wọn ṣe idanwo eto iṣegun oyinbo, ati iku lati ọwọ àwọn oṣiṣẹ alaabo SS.

O le ni ẹgbẹrun lọ́nà igba eeyan to lọ si ẹwọn, lara wọn si ni awọn ẹlẹwọn oṣelu, ẹya Júù, Roma ati Sinti.

Bo tilẹ jẹ pe Josef ni oun ko jẹbi àwọn ẹ̀sùn naa, Onidajọ Udo Lechtermann sọ pe iwadii ile ẹjọ fihan pe o ṣiṣẹ ni ibudo naa fun bi ọdun mẹta, bẹ̀rẹ̀ lati ọdun 1942.

Adajọ ni "O finu findọ ṣe atilẹyin fun pipa ọpọ eeyan, nipasẹ isẹ oojọ rẹ."

Ọdun 2011 ni anfaani bẹ̀rẹ̀, lati ṣe igbẹjọ àwọn ọmọ ogun Nazi, lẹyin ti ile ẹjọ́ rii pe ọmọ ogun SS kan, John Demjanjuk jẹbi.

Idajọ rẹ lo mu ki wọn o bẹ̀rẹ̀ si wa àwọn to ṣi wa laye.

Ọdún mẹrin lẹ́yìn igba naa, wọn fi akọ̀wé Auschwitz, Oskar Gröning, si ẹwọn.

Akọwe kan ni ibudo naa, to ti pe ẹni ọdun mẹtadinlọgọrun bayii n jẹjọ ni Ariwa Germany.

Botilẹ jẹ pe orúkọ ati akọsilẹ nipa ìbí Josef wa ni akọsilẹ nileeṣẹ alaabo SS, o ni oun ko ṣiṣẹ ri ni ibudo naa.

Ọkùnrin naa sọ pe alagbaro ni oun lóko kan.

Ko tii daju boya yoo ṣe ẹwọn, nitori pe ile ẹjọ́ to ga ju ni Germany gbọdọ sọ boya o ni anfaani lati pe ẹjọ́ kotẹmi lọrun. Igbeṣẹ naa yoo si gba ọpọlọpọ oṣu.