Donald Trump mọ̀ nípà ìkolù sí Capitol Hill ní Amerika – Òṣìṣẹ́ Trump

Jan 6 hearings: Òṣìṣẹ́ Trump ní Donald Trump nò nípà ìkolù sí Capitol Hill ní Amerika

Aworan Trump

Oríṣun àwòrán, Google

Ajọ to n gbọ ẹsun ikọlu si awọn aṣofin nilẹ Amerika ni ọjọ Kefa, Osu Kini, ọdun to kọja tẹsiwaju ni ile igbimọ aṣofin.

Titi di asiko yii ni ajọ naa ṣẹṣẹ ri ẹri nipa ipa ti aarẹ Trump ko ninu ikọlu si Capitol Hill nibi ti awọn aṣofin ti n ṣe ipade nipa eto idibo to gbe aarẹ Joe Biden wọle.

Ọkan ninu awọn ẹlẹri to sọrọ ni Cassidy Hutchinson,to jẹ oṣiṣẹ agba si adari oṣiṣẹ ni ileeṣẹ aarẹ lasiko aarẹ Donald Trump.

Lara ọrọ ti o sọ nipe aarẹ Trump fẹ fi tipatipa yi ijanu ọkọ gba lọwọ awọn ẹṣọ alaabo ninu ọkọ lasiko ti iwọde n lọ lọwọ ni Capitol Hill.

Ajọ to n gbọ ẹsun ikọlu si awọn aṣofin nilẹ Amerika ni ọjọ Kefa, Osu Kini, ọdun to kọja tẹsiwaju ni ile igbimọ aṣofin.

Titi di asiko yii ni ajọ naa ṣẹṣẹ ri ẹri nipa ipa ti aarẹ Trump ko ninu ikọlu si Capitol Hill nibi ti awọn aṣofin ti n ṣe ipade nipa eto idibo to gbe aarẹ Joe Biden wọle.

Ọkan ninu awọn ẹlẹri to sọrọ ni Cassidy Hutchinson,to jẹ oṣiṣẹ agba si adari oṣiṣẹ ni ileeṣẹ aarẹ lasiko aarẹ Donald Trump.

Lara ọrọ ti o sọ pe aarẹ Trump fẹ fi tipatipa yi ijanu ọkọ gba lọwọ awọn ẹṣọ alaabo ninu ọkọ lasiko ti iwọde n lọ lọwọ ni Capitol Hill.

Arabinrin naa ni ọga ohun, Mark Meadows ni oṣeeṣe ki awọn eniyan ṣe ikọlu pẹlu bi ifẹhọnuhan ṣe n lọ lọwọ.

Wọn ohun ti aarẹ Trump sọ ni ọjọ naa ni wi pe ko si ohun to kan ohun nitori pe awọn eniyan naa ko kọju ija si ohun.

O kere tan eniyan kan sọ ẹmi rẹ nu ninu ikọlu si Capital Hill

Bakan naa ni arabinrin naa ni Trump mọ lara awọn eniyan to sekọlu naa.

Wọn ni o sọ wi pe ; ‘’ Ko si ohun to kan mi nipa pe awọn eniyan gbe ohun ija lọwọ, wọn ko wa si ibi lati ṣekọlu si mi’’

Arabinrin Cassidy Hutchinson ni Trump pe awọn afẹhọnuhan naa ni awọn eniyan ohun ati wi pe ki wọn je ki wọn ṣewọde lati White House lọ si Capitol Hill.

Amọ bi arabinrin naa ṣe n sọrọ lọ ni aarẹ tẹlẹ naa, Donald Trump n kọ si oju opo Twitter rẹ pe ko si otitọ kankan ninu ọrọ ẹri arabinrin Cassidy Hutchinson.

Nibayii, Ajọ to n gbọ ẹsun naa ti kesi awọn araalu ati oṣiṣẹ to fi mọ awọn to sunmọ aarẹ Donald Trump lati wa sọ ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ ọdun to kọja naa.

O kere tan eniyan kan sọ ẹmi rẹ nu ninu ikọlu si Capital Hill naa ni ọpọlọpọ aṣofin si farapa