You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni Facebook ṣe fún Femi Falana, tó fi wọ́ Meta lọ sìlè ẹjọ̀?
Agbẹjọro ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti pe ileeṣẹ Meta Platforms Inc, ileeṣẹ to ni ikanni ayelujara Facebook lẹjọ.
Miliọnu marun un dọla ni Falana n beere fun bi wọn se tako ofin to lodi si titoju bọ asiri ikọkọ rẹ.
Falana fẹsun kan Meta pe, wọn lo awọran rẹ, orukọ ati ohun rẹ, fi ṣe ipolowo ayederu oja kan lori ikanni wọn.
Falana fikun pe, oju opo naa ni oun ni aisan inu wiwu, Protatitis, aisan to ni oun ko fi igba kankan ni ri.
Ninu iwe ẹjọ naa to gbe lọ si ileẹjọ giga to wa nipinlẹ Eko ni ọjọ kẹta oṣu keji ọdun 2025, Falana ni bi Facebook se lo aworan rẹ tako ofin ẹtọ ọmọniyan labẹ ofin ọdun 1999.
"Oju opo AfriCare Health Centre sọ pe mo ti ni aisan fun ọdun mẹrindinlogun, to si n la ọpọ inira kọja"
Falana fẹsun kan Meta pe wọn n gbe irọ sita, ti wọn si n si ọpọ lọna pẹlu ikanni ti wọn pe ni AfriCare Health Centre ti wọn da silẹ lori Facebook.
Oju opo naa lo sọ pe Falana ti ni aisan fun ọdun mẹrindinlogun , to si jẹ pe o n la ọpọ inira kọja.
O sọ ninu iwe ẹjọ to fi pe Meta, o ni oun ko fi igba kankan ni iṣoro pẹlu ilera rẹ, ati pe fidio ti wọn gbe sita lo jẹ ayederu, to si n si ọpọ lọna.
Falana ni o ye ki Meta wa idi otitọ ko to di pe wọn gbe irufẹ iroyin naa sita lori ayelujara.
O fẹsun kan gbigbe iroyin ẹlẹjẹ naa si ta lo da lori erongba lati pa owo wọle fun ikanni Facebook.
Ile ẹjọ o ti mu ọjọ ti igbẹjọ naa yoo waye.