Fífi òfin de ìwé ẹ̀rí láti Benin àti Togo yóò ṣe àkóbá fún akẹ́kọ̀ọ́ 15,000 - NANS

Oríṣun àwòrán, AFP
Ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria, NANS, ẹka ti orilẹede olominira Benin ti kesi ijọba apapọ lati juwọ ofin to wọgile bibuwọlu iwe ẹri lati fasiti lati orilẹede Togo ati Benin.
Aarẹ NANs orilẹede olominira Benin, Ugochukwu Favor lo sọ eyi lasiko to n ba ileeṣẹ Channels sọrọ.
O ni igbesẹ ijọba apapọ yii yoo se akoba nla fun awọn akẹkọọ to le ẹgbẹrun mẹdogun ti wọn kẹkọ lorilẹede Benin.
Lati ọsẹ to kọja ni awuyewuye ti n waye lẹyin ti akọroyin kan tu aṣiri bo sẹ gba iwe ẹri fasiti laarin oṣu meji pere, lati ile ẹkọ kan ni orilẹ-ede Benin Republic.
Lẹyin ti asiri naa tu sita ni Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti da eto ṣiṣe agbeyẹwo ati bibuwọlu awọn iwe ẹri fasiti to wa lati orilẹ-ede Benin ati Togo.
Ileeṣẹ eto ẹkọ ni Naijiria kede idaduro naa ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ni ọjọ Iṣẹgun. ọjọ keji, oṣu Kinni, ọ̀un 2024.
Ugochukwu ni ki ijọba ro ti awọn akẹkọọ ti wọn wa lorilẹede yii ti n jẹ anfani eto ẹkọ ọfẹ, ti wọn si n gba ẹkọ lọwọ.
“Ohun ti mo fẹ sọ ni pe ki ijọba dasi ọrọ yii, ko ṣeeṣe ki irufẹ isẹlẹ maa waye ni gbogbo awọn fasiti, ti igbesẹ yoo se akoba fun gbogbo awọn akẹkọọ.
“Akẹkọọ ẹgbẹrun mẹdogun ni igbesẹ yoo se akoba fun ni orilẹede Benin.”















