You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Mo mọ̀ pé agbede méjì ayé àti ọ̀run ni mo wà lásìkò tí mo bá n bímọ'
- Author, Makuochi Okafor
- Role, BBC Africa health correspondent, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélógún, Nafisa Salahu kò bá di ọ̀kan lára àwọn òǹkà àwọn obìnrin tó pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ìbímọ.
Ní Nàìjíríà, láàárín ìṣẹ́jú méje síra ni obìnrin ń kú lásìkò tí wọ́n bá ń rọbí tàbí ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tán.
Àsìkò tí àwọn dókítà n yanṣẹ́lódì ni Nafisa Salahu bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, láì sí àrídájú dókítà nílé ìwòsàn.
Orí ọmọ Nafisa Salahu há sí i lábẹ́, síbẹ̀ wọ́n ní kó wà lórí ibùsùn tó ti ń rọbí fún ọjọ́ mẹ́ta.
Nígbẹ̀yìn, wọ́n rí dókítà kan tó gbà láti ṣe iṣẹ́ abẹ fún-un.
"Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí mó de ọ̀run bọ̀. Mi ò ní okun kankan mọ́," abílékọ Salahu sọ fún BBC láti ìpínlẹ̀ Kano, ẹkùn àríwá Nàìjíríà.
Bí ó tiẹ̀ jẹ́ pé Salahu móríbọ́ lọ́wọ́ ikú, ọmọ rẹ̀ kò yè, ó pádànú ọmọ náà.
Ọdún mọ́kànlá lẹ́yìn ìgbà náà, Salahu ti lọ sílé ìwòsàn lọ́pọ̀ ìgbà láti lọ bímọ, tó sì máa ń lọ pẹ̀lú iyè méjì. "Mo mọ̀ pé ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ni mo wà ṣùgbọ́n ẹ̀rù kìí bà mí mọ́," ó sọ.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nafisa Salahu kìí ṣe ohun tuntun ní Nàìjíríà.
Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè tó léwu jùlọ ní àgbáyé láti bímọ sí.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN, èyí tí wọ́n ṣe àkójó rẹ̀ lọ́dún 2023 ṣe sọ, obìnrin kan nínú ọgọ́rùn-ún obìnrin ló ń pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò ìbímọ tàbí lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n bá bímọ tán, èyí tó mú Nàìjíríà wà ní òkè tábìlì tí orílẹ̀ èdè kankan kò fẹ́ dúró sí.
Lọ́dún 2023, Nàìjíríà ni ìdá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29%) àwọn obìnrin tó pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ìbímọ káàkiri àgbáyé ti wáyé.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé obìnrin 75,000 ló jáde láyé lásìkò ìbímọ láàárín ọdún kan - tó túmọ̀ sí pé àwọn ìyá ọmọ tuntun ń kú láàárín ìṣẹ́jú méje síra wọn.
Ìkìlọ̀: Àwòrán ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ̀bí rẹ̀ wà nínú ìròyìn yìí
Ohun tó ń bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú lórí àwọn ikú yìí kò ṣẹ̀yìn pé, àwọn nǹkan tó ń ṣokùnfà ikú àwọn ìyá tuntun bíi àpọ̀jù ẹ̀jẹ̀ lẹ́yìn ọmọ bíbí, jẹ àwọn nǹkan tó ṣe é dènà.
Ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì ni Chinenye Nweze nígbà tó jáde láyé nítorí ẹ̀jẹ̀ tó ń ya lára rẹ̀ lẹ́yìn tó bímọ tán ní ìlú Onitsha lẹ́kùn ìlà oòrùn Nàìjíríà ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn.
"Àwọn dókítà nílò ẹ̀jẹ̀," àbúrò rẹ̀ Henry Edeh ṣèrántí. "Ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ní níll kò tó tí wan sì ń sáré kiri láti wá ẹ̀jẹ̀. Pípàdánù ẹ̀gbọ́n àti ẹ̀rẹ́ mi jẹ́ ohun tí mol è gbèrò fún ọ̀tá mi."
Lára àwọn ohun tó máa ń fa ikú iyá ọmọ tuntun, tó wọ́pọ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rúru, wáhàlá lásìkò ìrọbí àti oyún ṣíṣẹ́.
Gẹ́gẹ́ bí Martin Dohlsten láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé láti àjọ UN, Unicef ní Nàìjíríà ṣe sọ, nǹkan tó pọ̀ ló ṣokùnfà ìdí tí àwọn obìnrin ṣe ń pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ìbímọ.
Lára àwọn nǹkan tó kà ni àìsí ilé ìwòsàn tó tó, àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera tí kò tó, ìtọ́jú ètò ìlera tó wọ́n gógó tí ọ̀pọ̀ kò lè san rí owó rẹ̀ san, àwọn àṣà tí kò mú kí àwọn èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú òṣìṣẹ́ ìlera àti àìsí ààbò.
"Kò sí obìnrin tó yẹ láti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò ìbímọ," Mabel Onwuemena, tó jẹ́ alákòóso ètò Women of Purpose Development Foundation sọ.
Ó ṣàlàyé pé àwọn obìnrin kan, pàápàá ní abúlé gbàgbọ́ pé fífi àkókò ṣòfò ni lílọ sí ilé ìwòsàn jẹ́ tí wọ́n sì máa fẹ́ràn láti lọ sọ́dọ̀ àwọn agbẹ̀bí ìbílẹ̀ dípò lílọ sí ilé ìwòsàn.
Fún àwọn míì, kò ságbára fún wọn láti lọ sílé ìwòsàn nítorí àìní owó ọkọ̀ tí Onwuemena sì gbàgbọ́ pé àwọn tí wọ́n rówó àti lọ pàápàá nígbà míì kìí rí ìṣòro wọn tán níbẹ̀.
"Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìwòsàn ni kò ní àwọn ohun èlò tó yẹ àtàwọn òṣìṣẹ́ tọ kájú òṣùwọ̀n, eyí tó máa ń mu nira láti pèsè iṣẹ́ tó dára."
Ìdá márùn-ún (5%) ètò ìsúná Nàìjíríà ni ìjọba ń ná órí ètò ìlera – èyí tó kéré púpọ̀ sí ìdá mẹ́ẹ̀dógún tó jẹ́ àfojúsùn tí ìjọba tọwọ́bọ àdéhùn lé lórí pẹ̀lú àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Africa lọ́dún 2001.
Lọ́dún 2021, àwọn agbẹ̀bí 121,000 ló wà ní Nàìjíríà tó ní èèyàn mílíọ̀nù 218 tó sì jẹ́ pé kò tó ìlàjì gbogbo àwọn tó lọ́dún náà tó jẹ́ pé agbẹ̀bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ló gbẹ̀bí wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí àjọ ètò ìlera àgbáyé gbé kalẹ̀, Nàìjíríà nílò àwọn nọ́ọ̀sì àti agbẹ̀bí 700,000 sí àwọn tó ti wà tẹ́lẹ̀.
Bákan náà kò sí àwọn dókítà tó tó ní Nàìjíríà.
"Mi ò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ilé ìwòsàn tó bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn ìròyìn nípa báwọn òṣìṣẹ́ kìí ṣe yà sáwọn èèyàn nílé ìwè ìwòsàn pàápàá àwọn tó jẹ́ ti ìjọba," Jamila Ishaq sọ.
"Bí àpẹẹrẹ nígbà tí mow à nínú oyún ọmọ mi kẹrin , àwọn kùdìẹ̀kudiẹ fẹ́ fáyé, agbẹ̀bí ìbílẹ̀ tí à ń lò gbà wá lámọ̀ràn pé kí a lọ sílé ìwòsàn àmọ́ a ò bá òṣìṣẹ́ kankan nígbà tí a débẹ̀. Mo padà sílé àmọ́ ibẹ̀ náà ni mo padà bímọ sí.
Ẹni ọdún méjìdínlógún náà tó ti wà nínú oyún karùn-ún sọ pé òun máa gbìyànjú láti lọ sílé ìwòsàn aládàni àmọ́ owó rẹ̀ pọ̀ púpọ̀.
Chiwende Obiejesi, tó wà nínú oyún ọmọ kẹta, ní àǹfàní láti lọ sí ilé ìwòsàn tó jẹ́ aládàni, tó sì ní òun kò lè bímọ síbò míì yàtọ̀ síbẹ̀.
Ó ní ikú ìyá ọmọ tuntun kò wọ́pọ̀ láàárín àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ òun.
Ní agbègbè àwọn ọlọ́rọ̀ ni Abuja ni Obiejesi ń gbé, àwọn ọ̀nà bẹ dára, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó ń gbé ní agbègbè náà ló ní ìmọ̀, tí wọ́n sì mọ pàtàkì lilọ sí ilé ìwòsàn.
Ó ní òun máa ń lọ fún àyẹ̀wò lóòrèkóòrè láti ṣàyẹ̀wò ìlera òun àti ti ọmọ.
Obiejesi sọ fún BBC pé nígbà tí òun wà nínú oyún ọmọ kejì, ìgbàgbọ́ wà pé ó ṣeéṣe kí ẹ̀jẹ̀ pọ̀ jù tí wọ́n sì ti wá ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ fún òun ṣùgbọ́n òun kò padà nílò rẹ̀.
Àmọ́ ó ní ọ̀rẹ́ ẹbí òun kàn kò rí irú àǹfàní bẹ́ẹ̀.
Nígbà tó ń rọbí, òṣìṣẹ́ ìlera kò ríbi gbẹ̀bí ọmọ náà tí wọ́n sì fẹ́ fi tipátipá yọ ọmọ náà síta. Nígbà tí wọ́n fi máa gbé ọmọ náà jáde ó ti pẹ́ púpọ̀ tó sì jẹ́ pé ọmọ náà ti kú sínú ìyá rẹ̀. Iṣẹ́ abẹ ni wọ́n fi padà gbé ọmọ náà jáde.
Dókítà Nana Sandah-Abubakar, adarí ètò ìlera ní ẹsẹ̀ kùkú ní iléeṣẹ́ tó wà fún ètò ìlera alábọ́dé ní Nàìjíríà, National Primary Health Care Development Agency gbà pé ìṣòro ńlá ni ọ̀rọ̀ náà àmọ́ tí wọ́n ti ń wá ọ̀nà àbáyọ sí wọn.
Ní oṣù Kọkànlá ọdún tó kójá ni ìjọba gbé ètò láti mú àdínkù bá ìkú ìyàlọ́mọ tí wọ́n pè ní Maternal Mortality Reduction Innovation Initiative (Mamii). Èròńgbà nip é èyí máa kojú àwọn ìjọba ìbílẹ̀ 172 ní ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) níbi tí ìlàjì ikú àwọn ìyálọ́mọ ti ń wáyé jùlọ.
"Ohun tí a ṣe ni pé a wá àwọn olóyún kàn, mọ ibi tí wọ́n ń gbé, ṣe àtìlẹyìn fún wọn nínú oyún, lásìkò ìbímọ àti lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ tán," Dókítà Sandah-Abubakar sọ.
Ó ní àwọn olóyún 400,000 ni àwọn ti ṣàwárí ní ìpínlẹ̀ mẹ́fà pẹ̀lú àkọ́ọ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ sílé ìwòsàn sí.
Ó ní ó jẹ́ ohun tó yá lásìkò láti máa ṣe ìgbéléwọ̀n ètò náà àmọ́ ìrètí wà pé Nàìjíríà náà máa tọpasẹ̀ àwọn orílẹ̀ èdè yòókù.
Lágbàáyé, àdínkù ti ń bá ikú ìyálọ́mọ láti ọdún 2000 pẹ̀lú ìdá ogójì (40%) tó sì rí bẹ́ẹ̀ ní Nàìjíríà náà àmọ́ pẹ̀lú mẹ́tàlá (13%).
Pẹ̀lú ètò Mamii àtàwọn ètò ìlera míì, àwọn onímọ̀ gbàgbọ́ pé ìdókoòwò sí ètò ìlera nílò láti pọ̀ si láti rí èsì tó dára.
Ní àsìkò yìí ná, pípàdánù ìyá igba (200) ní Nàìjíríà lójoojúmọ́ yóò máa jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fáwọ ẹbí tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá wáyé sí.
Fún Edeh pípàdánù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jẹ́ ohun tí kò lè tán ní ọkàn rẹ̀.
Ó ní òun ló ṣe ìtọ́jú àwọn nígbà tí àwọn pàdánù àwọn òbí àwọn lásìkò tí wọ́n ń dàgbà.
"Nígbà tí mob á rántí rẹ̀ lásìkò t imo bá dá wà, mo máa ń sun ẹkún kíkorò."