You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé o lè lóyún oṣù mẹ́jọ kí o má mọ̀? Ìdí rẹ̀ nìyí
- Author, Bonnie McLaren, BBC Newsbeat
- Role, BBC Newsbeat
Kii ṣe erongba Tawana ni lati bi ọmọ nigba to wa ninu oyun ọmọ rẹ, River.
Tawana ṣalaye pe oun n jaye ori oun lọ ni toun nipa lilọ ode ariya pẹlu awọn ọrẹ oun.
O ni ṣadeedee ni oun dero ile iwosan lẹyin ti oun ṣubu.
Nibẹ ni wọn ti sọ fun un pe, yoo bi ọmọ ni bi oṣu kan siwaju.
Tawana ni bayii ni oun bẹrẹ si ni bẹru.
Ko mọ rara wi pe oun wa ninu oyun.
Nigba ti o wa ni ile iwosan l'awọn dokita sọ pe ki o ṣe ayẹwo lati mọ bo ya o ti loyun.
Tawana kọ eti ikun si ọrọ awọn dokita, tori o n loogun ifetosọmọbibi, bẹẹ ni ko si ri àpẹẹrẹ kankan pe oun loyun.
Ọkan Tawana kọkọ balẹ diẹ, nigba ti esi ayẹwo oyun ti o ṣe ṣafihan pe ko si oyun lara rẹ.
Amọ, nọọsi kan lo gba dokita ni imọran wi pe ki ile iwosan naa ṣe ayẹwo mii to tun lagbara ju eyi ti wọn ti ṣe lọ tori o ṣeeṣe ki oyun wa lara rẹ.
Emmanuel to jẹ baba River sọ pe oun o gba iyawo oun gbọ nigba ti o sọ foun pe oun maa bímọ laipẹ.
O ni o ju ọgbọn ati oye oun lọ, "iyanu lo jẹ."
Oyun aimọ ni eeyan maa n ni nigba ti ko ri àpẹẹrẹ oyun nini bii ki eeyan maa bi tabi ki ikun maa yọ sita.
Ko saba wọ pọ, ṣugbọn Tawana ni awọn dokita sọ foun pe iru oyun bayii maa n saba waye laarin awọn obinrin alawọ dudu.
"Wọn sọ fun mi pe "nitori bi egungun wa ṣe ri, ọmọ maa n saba n dagba sinu awọn obinrin alawọ dudu, dipo ki oyun maa dagba sita," Tawana ṣalaye.
Tawana ni nigba to to asiko foun lati bímọ, ni oun bẹrẹ si kọminu lori bi ibimọ naa yoo ṣe lọ.
Bo tilẹ jẹ pe akọsilẹ ko pọ nipa nini oyun laimọ, Ọjọgbọn onimọ nipa eto ilera ni fasiti South Bank ni London, Alison Leary, sọ pe awọn àkọsílẹ kan wa lori iyatọ to maa n bara awọn obinrin kan nipo iloyun.
O ni "ọpọ iwadii lo fidi rẹ múlẹ pe iru oyun bayii wọpọ laarin awọn obinrin alawọ dudu."
"Idi gan an niyii ti o fi ṣe pataki ki awọn eeyan mọ nipa irufẹ oyun yii, bo tilẹ jẹ pe awọn obirin tọrọ naa kan ko pọ.
Oloyun ti ko ba ni anfani si eto ilera to muna doko, o ṣeeṣe ki o ma mọ wi pe oyun ti wa lara oun," Ọjọgbọn Leary ṣalaye.
Lẹyin ọsẹ mẹrin ati ọjọ mẹrin t'awọn dokita sọ fun Tawana pe yoo bímọ ni o bi ọmọ rẹ, River ni tootọ.
O ni ọkan oun daru lẹyin ti oun bi ọmọ naa tan.
Koda, o ni oun ni lati maa beere fun imoran lori itakun ayelujara TikTok lori ohun ti eeyan le ṣe ti o ba bímọ laipẹ si igba ti o mọ pe oun loyun.
Tawana ṣalaye pe obinrin kan ṣoṣo lati Amerika loun ri ti o sọ pe oun ti ni iru iriri yii ri.
"Ọkan mi daru tori ni ṣe lo dabi ẹni pe ko si ẹni to le fun mi ni imọran lori ohun ti mo n la kọja."
Tawana pada sọ iriri rẹ ninu fidio to fi lede lori itakun ayelujara eyi ti ọpọ eeyan fẹran.
O tun bẹrẹ si ni ṣe fidio mii eyi to fi n b'awọn obinrin to ti bímọ sọrọ.
Tawana ṣalaye pe oun ṣe fidio naa lati ṣe iranwọ fáwọn ọdọmọde obinrin ti wọn ba bímọ nigba ti wọn ko ni ireti lati ṣe bẹẹ.
O ni ohun to sẹlẹ si oun ko ni ipa to lagbara ju lori oun, tori mama oun ṣe iranwọ owo fun oun
Ṣugbọn o mọ pe ọpọ eeyan lo le ma ni iru anfani bayii.
Kinni wọn n pe ni oyun aimọ?
- Oyun aimọ jẹ oyun ti obinrin ni nigba ti oun gan an ko mọ pe oyun wa lara oun.
Awọn obinrin mii ko tiẹ ni mọ nkankan pe awọn ti loyun titi ti wọn yoo fi de wọọdu ti wọn yoo ti gbẹbi fun wọn.
Nkan bi ẹgbẹrun meji ati aabọ ọmọ ti wọn n bi lawọn iya wọn ko mọ pe awọn loyun.
Eyi tumọ si pe ọdunrun un awọn ọmọ bẹẹ ni wọn n bi ni UK lọdun kan.
Awọn mii maa n ṣẹlẹ nigba ti obinrin ba n ṣe wahala to pọ debi pe ko ni ri àpẹẹrẹ kankan wi pe oun loyun, tori awọn obinrin ti nnkan oṣu wọn maa n ṣe ṣege ṣege gan an maa n ri ami tabi àpẹẹrẹ pe awọn ti loyun.
Orisun iroyin yii: Ọjọgbọn onimọ nipa igbẹbi ni fasiti Stirling, Helen Cheyne.