Àìsàn f’òníkú-f’ọ̀la dìde Sickle cell: Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé

A ki i ró kadun. Iyẹn ni pe ko si bi eeyan yoo ti ṣe e ti yoo fi gbogbo ọdun lalaafia yipo. Bi ko ju ori fifọ, ara riro abi iba, yoo ṣeni kọdun too yipo.

Ṣugbọn aisan kan wa ti ko kan tasiko, igbakigba lo n sọ awọn to ba n ṣe wo, inira buruku ni wọn si maa n koju to ba ti de.

Aisan naa ni oyinbo n pe ni Sickle cell anaemia, ti Yoruba n pe ni f’oni-ku-f’ọla dide.

Foniku-fọla dide ko mọ ẹya tabi iran kan, ṣugbọn iran eeyan dudu lo maa n da laamu ju gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ.

O kere tan, eeyan 250m ni aisan yii n ba ja kaakiri agbaye, wọn si ka awọn ilẹ Adulawọ, Saudi Arabia, ilẹ India ati awọn ilu ti agbami okun gba kọja mọ ibi to pọ si.

Lorilẹ-ede Amẹrika, gbogbo ọmọ ikoko ti wọn ba n bi ni wọn n ṣayẹwo aisan yii fun bo ṣe n dele aye.

Aisan yii ko kere ninu aye rara, to bẹẹ ti wọn fi ya ọjọ fun un lagbaye, eyi ti wọn pe ni ‘World Sickle Cell anaemia day’’.

Gbogbo ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹfa ọdun ni ayajọ aisan yii lagbaaye.

Ti ọdun yii naa ti ko la ṣe ni ka da yin lẹkọọ nipa aisan to n mu eeyan gbadun lonii, ti yoo si dubulẹ aisan lọjọ keji bii ẹni ti ko gbadun ri.

Kí ni àìsàn f’òníkú-f’ọ̀la dìde?

Dokita Asmaa Ferdjallah, onimọ nipa ẹjẹ, jẹjẹrẹ ati itọju awọn ọmọde lọsibitu Mayo, ṣalaye pe ọkan lara awọn aisan ajogunba ni foniku-fọla dide.

O ṣalaye pe atẹ ẹjẹ pupa ara eeyan (Red blood cell)ni aisan yii maa n kọlu.

Rogodo lai ni igun kankan ni atẹ awọ pupa yii yẹ ko jẹ, ti eeyan yoo fi ni alaafia, nigba naa ni yoo le rọrun fun ẹjẹ naa lati gbe eemi (oxygen) kari gbogbo ara.

Ṣugbọn fun awọn ti aisan yii ba n ba ja, atẹ awọ pupa tiwọn ko ni i ṣe rogodo, yoo ni ibi kan to ti ge. Gige to ge yii ni yoo si maa ko inira ba wọn karikari gẹgẹ bi dokita ṣe sọ.

Ninu aworan to n ṣafihan aleebu to wa ninu atẹ ẹjẹ ti ko gun rege yii, apa ibi to ti yingin naa han kedere, o si da bii gọ̀gọ̀ ti wọn fi n ka koko loko, toyinbo n pe ni sickle.

Lara irinṣẹ Sickle yii ni wọn ti yọ orukọ aisan naa ti i ṣe Sickle Cell anaemia.

Kí làwọn àpẹẹrẹ tí ẹni tó ní àìsàn yìí yóò maa rí?

Akọsile lati ileewosan Mayo, ṣalaye pe nigba ti ọmọ ba wa loṣu marun-un si mẹfa ni apẹẹrẹ saaba maa n foju han pe aisan naa n ṣe ọmọ ọhun.

Nigba mi-in ẹwẹ, o le yatọ lati ara ẹnikan si ikeji.

Nibi oke eekanna ọwọ ọmọ naa ni Dokita Asmaa Ferdjallah, sọ pe yoo maa wu ti yoo si maa dun ọmọ naa.

Diẹ lara awọn apẹẹrẹ aisan foniku-fọla dide ree:

Àìtó ẹ̀jẹ̀ pupa lára (Anaemia): Ẹjẹ pupa to wa lara awa eeyan maa n yipada, ti eyi to wa lara yoo ku, omi-in yoo si rọpo rẹ laarin ọgọfa ọjọ (120 days). bi Iṣẹda ṣe ṣeto rẹ niyẹn.

Ṣugbọn fun awọn eeyan ti aisan yii n ba ja, laarin ọjọ mẹwaa si ogunjọ pere ni ẹjẹ pupa ara tiwọn fi maa n ku, eyi ko si ni i jẹ ki ẹjẹ to lara wọn. (anaemia).

Bi ẹjẹ pupa ko ba si ti to lara, eemi ti ara nilo ko ni i to, yoo si maa rẹ ẹni naa, ko ni i lagbara kankan.

Ara ríro tí kò ṣeé ṣàpèjúwe:

Ara riro ti yoo maa waye latigbadegba ti ko si ṣee ṣapejuwe bo ṣe nira to yoo maa koju ẹni to ni aisan foniku-fọla dide.

Irora yii maa n bẹrẹ nigba ti atẹ ẹjẹ pupa ba di oju opo to yẹ ki ẹjẹ tọ kari ara.

Ẹjẹ ti yoo maa kọja si ara ẹni naa ko ni to nnkan kan rara, eyi yoo bẹrẹ si i fa irora fun un ni aya, ibi idodo ati iṣan ara yooku.

Ara riro yatọ lati ara ẹnikan si ikeji ṣaa, gẹgẹ bi dokita ṣe wi.

Awọn mi-in n lo wakati lori rẹ ki wọn too gbadun, ọjọ bii meloo ni yoo si gba awọn mi-in ki wọn too ri alaafia.

To ba ti ri bayii, ileewosan lo kan ti ẹni naa yoo lọ, nibi ti wọn yoo da a duro si fun itọju.

Ọwọ́ àti ẹsẹ̀ yóò wú: Airin gaara ẹjẹ lara le fa ki ọwọ ati ẹsẹ ẹni to ni aisan yii wu.

Àwọn àìsàn tí kò yẹ kó gbéèyàn ṣánlẹ̀ yóò máa wáyé léraléra

Ẹya ara kan wa to maa n gbogun ti aisan ninu ara (spleen), aisan foniku-fọla dide maa n ṣakoba fun ẹya ara yii, yoo si jẹ ki aarẹ maa kọlu ẹni to ba n ṣe.

Àìtètè dàgbà bíi àwọn ẹgbẹ́ ẹni yòókù:

Ẹjẹ pupa kun fun awọn eroja to n mu idagbasoke wa, bi ko ba ti to lara, ọmọ o ni i dagba bii awọn ẹgbẹ rẹ.

Nigba ti awọn ẹgbẹ rẹ ba n di ọkunrin abi ọmọge, ọmọ to n foniku-fọla dide yoo da bii aburo wọn ni, idagbasoke tirẹ ko ni i ya rara nitori ohun to n ṣe e.

Àíriran dáadáa: Iran oju yoo dinku nigba ti aisan yii ba n da ara laamu, apa ibi iriran ti a mọ si ‘retina’ yoo ko si wahala, ẹni naa ko si ni i riran daadaa mọ.

Kí ló ń fa f’òníkú-f’ọ̀la dìde gan-an?

Nigba ti ayipada ba de si eroja hemoglobin to n pese ẹjẹ pupa ni iṣoro maa n wa.

Ṣugbọn gẹgẹ bi a ṣe sọ ṣiwaju, ajogunba ni aisan yii.

Bi ọmọ yoo ba ni aisan foniku-fọla dide, awọn obi rẹ mejeeji ni wọn ni iṣoro naa ti wọn si taari rẹ si ọmọ ti wọn bi latari ẹjẹ wọn to jẹ oriṣi kan naa.

To ba jẹ pe ẹnikan ninu awọn obi mejeeji lo taari aisan naa si ọmọ, irufẹ ẹjẹ meji ni ọmọ naa yoo ni.

Yoo ni ti hemoglobin ati ti foniku-fọla dide ti a n sọ.

Ẹjẹ awọn obi le ni foniku-fọla dide diẹ ninu, ṣugbọn awọn apẹẹrẹ naa ko ni i han lara wọn nita.

Awọn obi bi eyi n ni aisan naa lara ni, (carrier), awọn ọmọ wọn si le koju aisan yii.

Àwọn ìṣòro míràn tí àìsàn yìí lè mú wá

Gẹgẹ bi alaye Dokita Ferdjallah nipa aisan yii, wọn lo ṣee ṣe ki foniku-fọla dide bi:

Rọpárọsẹ̀:

Eyi le ṣẹlẹ nigba ti ẹjẹ ko ba de ọpọlọ bo ṣe yẹ. Eeyan le daku, ọwọ ati ẹsẹ rẹ le ku taitai, o le ma le sọrọ mọ , o si le daku lọ gbari.

Bi ọmọ rẹ ba n fi eyikeyi ninu awọn apẹẹrẹ yii han, tete gbe e lọ ri dokita rẹ. Rọpa rọsẹ le ja si iku.

Àìlè mí dáadáa: Aya riro, iba ati aile mi daadaa le waye. Ẹ tete gba ọdọ dokita lọ.

Itan riro, ẹjẹ riru, ẹya ara bii kidinrin ati ẹdọ le ko si iṣoro bi ẹjẹ ko ba debẹ. Eyi le fa iku bi dokita ṣe wi

Ojú èeyàn lè fọ́:Alaboyun to ni aisan yii le padanu oyun naa, o le bimọ lai tọjọ, o si le bimọ naa ko kere jọjọ.

Báwo lo ṣe lè dènà àìsàn f’òníkú-f’ọ̀la dìde?

  • Bi o ba ni apẹẹrẹ aisan yii lara, yoo dara ki o kọkọ lọọ ri onimọ ẹya ara nipa iru eeyan ti o le fẹ (Genetic counsellor).
  • Onimọ nipa iṣoro yii yoo le la ọ lọye lori ewu to wa ninu fifẹ ẹni to ni iru iṣoro kan naa bii tirẹ.
  • Maa lọ sileewosan lati gba itọju loorekoore.
  • Jinna si awọn ohun to le ko ba alaafia rẹ nipa ohun jijẹ ati mimu.
  • Ma ṣe fi oogun ti wọn ba fun ọ silẹ lai lo.
  • Ma ṣe dawọle iṣẹ to ba lagbara ju fun ilera rẹ.