Peter Obi sọ pe íjọba Tinubu tó fẹ́ẹ́ ra bààlúù fún iléeṣẹ́ ààrẹ kò rí ti Nàìjíríà rò

Peter Obi, oludije ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ni 2023, ti koro oju si arakun baaluu ti ileeṣẹ aarẹ fẹẹ ra fun Aarẹ Bola Tinubu ati Igbakeji rẹ, Kashim Shettima.

Obi ṣapejuwe igbesẹ naa bi eyi ti ko ro ti awọn ọmọ Naijiria rara, to kun fun inira ṣugbọn to gbe ọrọ awọn eeyan to wa nipo si ookan aya rẹ.

Bakan naa lo fi aidunnu rẹ han si ile igbimọ aṣoju ti wọn lo n ṣagbatẹru igbesẹ ọhun.

Oju opo X rẹ ni oludije ipo aarẹ ninu ẹgbẹ Labour naa ti sọrọ yii lọjọ Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹfa ọdun 2024 yii.

’’Lásìkò tí orúkọ orílẹ̀èdè wa ti bàjẹ́ lókè òkun látàrí ọrọ̀ ajé tó dẹnukọlẹ̀ lẹ tún fẹ́ẹ́ ra bààlúù’’

Ninu ọrọ naa ni Peter Obi ti sọ pe lasiko yii ti orukọ Naijiria ti bajẹ loke okun nitori ọrọ aje to dẹnukọlẹ ni ileeṣẹ aarẹ tun fẹẹ ra baaluu.

‘’Iṣoro to n koju ọrọ aje wa latari bi gbogbo nnkan ṣe n wọn si i wa nibẹ.

Owo naira to ti bajẹ tan ati bi mẹkunnu ṣe n jiya wa nibẹ pẹlu, ṣugbọn ohun tijọba n ronu ni tiẹ ni bi yoo ṣe ra kun awọn baaluu to wa nilẹ nileeṣẹ aarẹ.

‘’Ai ka iṣoro to n koju araalu kun leyi’’

‘’Loootọ ni pe ọdun mejila ni awọn baaluu yii maa n lo, ṣugbọn lasiko ti owo wa lọwọ awọn araalu lati ra awọn ohun ti wọn nilo ni wọn ra awọn eyi to wa nibẹ yii.

‘’Ki i ṣe iru asiko yii ti adojukọ pọ fun Naijiria pẹlu gbese.

''Ara n ni araalu, ba a ṣe maa yanju iṣoro wọn lo yẹ ka maa wa, ki i ṣe pe ka maa di kun iṣoro wọn.’’

Bayii ni ondupo aarẹ lọdun 2023 naa wi.

Peter Obi sọ pe eto ẹkọ,ilera, lile ìṣẹ́ ati òṣì danu lo yẹ ko jẹ ijọba logun bayii, ki i ṣe ki wọn maa ni awọn eeyan Naijiria lara.

Igbimọ to n ri si aabo ilu nile igbimọ aṣoju la gbọ pe o gba ileeṣẹ aarẹ nimọran lati ra baaluu tuntun naa.