You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Báyìí ni wọ́n ṣe bá òkú ọmọ ọdún 15 ní ẹ̀yìnkùnlé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti ṣàwárí òkú ọmọdébìnrin kan ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dógún tí wọ́n ti ń fi ìgbà kan wá.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè South Africa sọ pe Cyferskull Precint, North West ṣe àwárí òkú Karabo Monyama ní ẹ̀yìnkùlé ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ níbi tí wọ́n sin-ín sí.
Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù Kẹta ni wọ́n rí òkú ọmọbìnrin náà ní ẹ̀yìnkùlé ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tó sì ti ń jẹrà.
Àwọn aláṣẹ ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Kẹta ni wọ́n ti rí Karabo kẹ́yìn ní nǹkan bíi aago kan ọ̀sán nígbà tó kúrò nílé láti lọ wo bọ́ọ̀lù ní pápá ìṣeré kan àmọ́ tí kò padà sílé láti ìgbà náà.
Ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ náà ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá, tó sì ń kojú ẹ̀sùn ìpàníyàn àti gbígbèrò láti fọwọ́ bo òfin mọ́lẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn iléeṣẹ́ News24, agbẹnusọ ọlọ̀pàá Amanda Funani ní àwọn ọlọ́pàá ti ṣaájú lọ sí ilé ọmọkùnrin náà láti bèèrè nípa Karabo lọ́wọ́ rẹ̀.
Funani sọ pé “ó parọ́ pé òun kò mọ ẹni tó ń jẹ́ Karabo àmọ́ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá tún padà ló sí ilé rẹ̀ ní ojọ́rú ló jẹ́wọ́ pé òun sín Karabo sínú kòtò kan ni.”
Ní ọjọ́ Ẹtì ni ọ̀rẹ́kùnrin náà fojú ba ilé ẹjọ́ Májísírèètì.
Karabo Monyama àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ náà ni wọ́n jọ ń gbé ní agbègbè kan náà, tí ọmọkùnrin náà sì ń gbé pẹ̀lú ìyá-ìyá rẹ̀.
Funani sọ pé àwọn ará àdúgbò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn rí Karabo lẹ́yìn tí bọ́ọ̀lù tó lọ wò parí pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ náà.
Ó ṣàlàyé pé ní àárọ̀ ọjọ́bọ̀ ni àwọn ẹbí Karabo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ àwọn ni.
“Ara rẹ̀ ti ń jẹra dada, aṣọ àti àmì kan tó wà ní ara rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ fi mọ̀ pé ọmọ àwọn ni.”
Funani ní ikú ọmọbìnrin náà jẹ́ àdánù ńlá fún àwọn òbí rẹ̀ tó sì tún báwọn ní òjìjì pẹ̀lú.
Ó fi kun un pé màmá Karabo kò mọ̀ nípa ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ tó wà ní àárín ọmọ rẹ̀ àti ọmọkùnrin náà.