You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun méje tó mú ilẹ̀ ríri ní Myanmar fa ikú rẹpẹtẹ tó lé ní 1,700
Niṣe ni onka iku awọn eeyan to ku nibi ile to wo ni Myanmar n pọ si i : Nigba ti yoo fi di alẹ ọjọ Ẹti, o kere tan, eeyan ọgọrun-un kan le mẹrinlelogoji (144 ) ni wọn ti ku, ti ọpọ si tun farapa, gẹgẹ bi ikọ ologun Myanmar ṣe sọ, bẹẹ ni wọn ṣi n ri awọn eeyan ti ikọlu yii tun kan niluu amuleti wọn ti i ṣe Thailand.
Awọn aworan to n jade n ṣafihan bi ọpọ ile ṣe ti bajẹ pẹlu awọn ọna, ni olu ilu Thai, Bangkok ni ile alaja ọgbọn (30-storey) ti wọn n kọ lọwọ ti wo lulẹ.
Ni 2019, ilẹ riri ti ikọlu rẹ to 7.1-ṣẹlẹ ni California, sibẹ, ẹnikan kan o ku, bẹẹ ni ko da wahala silẹ lẹka nnkan amayedẹrun.
Ṣugbọn ti Myanmar to ṣẹlẹ to paayan rẹpẹtẹ yii ni awọn idi kan to fi le to bẹẹ. Eyi ni awọn pataki ninu idi naa.
Bó ṣe jìn tó àti bí yóò ṣe pẹ́ tó
Kinni kan ti a mọ si Moment Magnitude Scale (Mw) ni wọn fi n ṣe odinwọn ilẹ riri to ba waye. Eyi lo rọpo eyi ti ọpọ eeyan mọ si Richter scale ti wọn n lo tẹlẹ, ti wọn si ti kọ ti bayii nitori ọjọ ti lọ lorii rẹ.
Bi ilẹ riri yoo ṣe lagbara to tun ni i ṣe pẹlu bo ba ṣe jinna silẹ to, ati bi ohun to n fa a ṣe le to.
Ilẹ to n mi lodiwọn 2.5 ko ṣee mọ lara, ṣugbọn bi wọn ba lo irinṣe to n tọka iru nnkan bẹẹ yoo fi han. Ilẹ riri to ba mọ niwọn marun-un ṣee mọ lara, o si le fa ijamba diẹ.
Ilẹ riri Tibet to wọ 7.1 ki i ṣe kekere, eyi to si ṣẹlẹ ni Guusu Turkey ati Syria loṣu Keji ọdun 2023 lagbara pẹlu.
Ilẹ riri yoowu to ba ju odiwọn mẹjọ lọ jẹ agbayanu, o si maa n fa ijamba la to le pa ibi to ti ṣẹlẹ run, awọn alamuleti rẹ paapaa yoo si faragba nibẹ.
Bakan naa ni bi ilẹ riri naa ba ṣe pẹ to lasiko to n waye, ni i ṣe pẹlu agbara rẹ ati ipa ti yoo ni.
"Bi ilẹ riri kekere ko ṣe ki n fi bẹẹ nipa to ti ko si ki n lo ju iṣẹju diẹ lọ, ilẹ riri alagbara to le mọ niwọn to si le pẹ, iru eyi to waye ni Saumatra ni 2024 le pẹ diẹ ko too dakẹ" Gẹgẹ bi ileeṣẹ Pacific Northwest Seismic Network ṣe sọ.
Jínjìn
Ki i ṣe bi ilẹ riri naa ṣe to nikan lo ṣe pataki: Aaye ti aye duro si lasiko ti ilẹ riri ọhun n waye naa tun ṣe pataki.
Ninu ilẹ riri to waye ni Morocco, ipo ti ilẹ riri ti n waye, wa laaaarin kilomita mejidinlogun (18km) si isalẹ aye. Giga eyi si fẹrẹ to ti ori oke Everest,ṣugbọn ko jin bi a ba fojuu aaye wo o.
"Ilẹ riri yii ko jin. Iyẹn tumọ si pe aye to wa kere lati gba ohun to n ṣẹlẹ mọra." Dokita Carmen Solana, onimọ nipa ilẹ riri ati aato agbegbe ni Yunifasiti Portsmouth, lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
Lodi si eyi, ilẹ riri oni 6.2 to ṣẹlẹ si agbegbe Ariwa Maluku, ni Indonesia loṣu Kẹsan-an ọdun 2023, jin ni iwọn 168km. Ẹnikan ko si ku..
Àsìkò tó ṣẹlẹ̀
Ilẹ riri to ṣẹlẹ ni Aarin gbungbun Morocco waye laago mọkanla kọja iṣẹju mọkanla, bi a ba lo aago agbegbe wọn. Eyi ṣee ṣe ko nipa lorii bi yoo ṣe pa eeyan to.
"Ọpọ ile ni ko ba bajẹ lasiko tawọn eeyan ba n sun" Dokita Solana lo sọ bẹẹ.
Ọpọ awọn to ku ninu ilẹ riri naa ku latari ile to wo lu wọn. Koda, awọn onimọ nipa ilẹ riri maa n sọ pe ki i ṣe ilẹ riri lo n pa eeyan, bi ko ṣe ile to n wo.
Fun idi eyi, ilẹ riri to ba ṣẹlẹ loju ọsan ki i sabaa pa eeyan pupọ bi eyi to ṣẹlẹ nigba ti ọpọ eeyan ba wa ninu ile.
Ilé kíkọ́
O ṣe pataki lati kọ ile ti yoo ri ara gba oriṣiiriṣii idojukọ, koda, ti yoo le koju ilẹ riri to lagbara ju. Ṣugbọn ki eyi to le ṣee ṣe, ile kikọ gbọdọ fa gbogbo agbara to ba yẹ lori ilé mọra.
Gẹgẹ bi iwadii awọn onimọ nipa ile kikọ ni US ṣe wi, iyẹn US Geological Survey (USGS), wọn ni orilẹede Japan ṣi ni ibi ti ilẹ riri ti le waye ju lagbaaye, ṣugbọn wọn ti mọ eyi wọn si ti kọ awọn ile alagbara to le koju ilẹ riri.
"Ni ti ile ba ti lagbara lati fa gbogbo ohun to le fa ilẹ riri sinu, ko ni i wo." Jun Sato, onimọ nipa aato ile kan lo sọ bẹẹ ni Yunifasiti Tokyo.
Lati ri eyi ṣe, ilana ikọle naa maa n yatọ. Wọn le ko bulọọku to nipọn ni ida 30-50cm wọn yoo fi kọle naa ko le baaa ri agbra koju ilẹ riri.
Ṣugbọn ilana yii wọn, o maa n nilo owo pupọ.
Ni apa ibi to wọnu ni Morocco, ti ọṣẹ nka ti ṣe wọn, ile alamọ lo pọ nibẹ, eyi ti ko le ri ara gba ilẹ riri to ba de.
Iku kekere kọ lo maa n ti ara ile gogoro jade nigba ti awọn eeyan ba wa nibẹ ti wọn n ṣe twiwọn lọwọ ti ile si dawo.
Ọpọ eeyan ni Turky naa jẹbi kikọ ile lai tẹle ilana ikọle, nigba ti ile wo nibẹ ni 2023 leyi foju han. Awọn alaṣẹ naa ko fi ofin de ilana ikọle ti wọn ko fẹ.
Loootọ ni ilẹ riri naa lagbara, ṣugbọn awọn onimọ sọ pe bi wọn ba lagbara ni, wọn ko ni i wo.
"Ilẹ riri yii lagbara loootọ, ṣugbọn ko le to lati mu ile ti wọn ba kọ daadaa wo"
Ọjọgbọn David Alexander, onimọ nipa ato ile ni pajawiri lo sọ bẹẹ ni Yunifasiti London.
Bí èèyán ṣe pọ̀ tó
Ilẹ riri nla kan waye to to 8.2, nitosi Alaskan peninsula loṣu Keje 2021, ṣugbọn o ṣee ṣe keeyan ma ranti.
Ilẹ riri Chignik ni wọn ni oun ni ẹlẹẹkeje to lagbara ju ninu itan ilẹ US, ṣugbọn ko pa eeyan bẹẹ ni ko ṣe ẹnikẹni leṣe. Ki lo fa a, idi ni pe awọn eeyan ko pọ nibẹ. O jinna sibi tawọn eeyan wa.
Lodi si eyi, ilẹ riri odiwọn 7.0 to ṣẹlẹ ni Haiti loṣu Kin-in-ni ọdun 2010 , pa ọpọ eeyan bii aadọta le ni igba ẹgbẹrun(250,000), eeyan ẹgbẹrun lọna ọọdunrun( 300,000) farapa, awọn 1.5 miliọnu to ṣẹku ko si nile lori mọ .
Yẹ̀pẹ̀
Bi ilẹ ba ṣe lagbara si ni yoo sọ bi a ṣe le bọ lọwọ ilẹ riri si.
Bi ilẹ ko ba le, ti yẹpẹ ko fara mọra, ko ni i si agbara lati gba ikọlu, gẹgẹ bi awọn USGS ṣe sọ, wọn ni eyi yoo si mu ki ilẹ maa mì.
Eeyan to le ni ẹgbẹrun lọna aadọta lo ku ni Turkey ninu ilẹ riri 2023 , ṣugbọn ilu ti wọn n pe ni Erzin - ti ko ju 80km sibẹ lọ si yege lai jẹ pe nnkan kan ṣe wọn.
Ko si ẹnikan bayii to ku niluu naa, bẹẹ ni ile kankan ko wo, awọn to yi i ka si parun.
Awọn onimọ sọ pe Erzin ye nitori ibi to wa, ati ori ilẹ lile to wa, eyi to ri ara gbe gbogbo iji lile to ja ọhun.
Ìdáhùn ní pàjáwìrì
Ki eeyan pọn omi silẹ de oungbẹ maa n dena ai ri omi mu lasiko ẹrun, bẹẹ naa lo ṣe ri fun ile riri.
Ni Japan, wọn ti kọ awọn akẹkọọ ni ọna ti wọn ke fi da aabo bo ara wọn bi ilẹ ba ri. Taiwan ni tiẹ ko wọn jade, wọn kọ wọn ni ilana yii kaakiri ilu naa.
Ṣugbọn eyi ko ri bẹẹ ni ọpọ orilẹede, paapaa lawọn ibi ti wọn ko ti n sabaa koju iṣoro bi eyi.
To ba ṣẹlẹ, bi awọn ikọ alabo ṣe n yara dahun si ipe pajawiri yii ṣe koko. Eyi to ṣẹlẹ ni Turkey, ọpọ eeyan lo ti ha si abẹ ile to jẹ lẹyin ojọ kẹwaa ni wọn too ri wọn gbe jade. Eeyan ko si le pẹ labẹ ilẹ to yẹn ko ma ku.
Fun idi eyi, ki ọkọ ti yoo le gbe awọn eeyan wa nikalẹ ṣe koko.
Ipa mí-ìn tó tún lè ní
Ile to n wo nikan kọ ni okunfa iku awọn eeyan nigba ti ilẹ ba ri
Apọju eeyan niluu naa le fa wahala bii tsunami.
Tsunami Asia to ṣẹlẹ ni 2004, waye latari ilẹ riri nla to wọ 9.1 labẹ omi okun India, nitosi Banda Aceh, loju ọna Sumatra.
Ilẹ riri nla to ṣẹlẹ pa eeyan to to 230,000 lawọn orilẹede to le ni mejila. Iji nla lo gbe wa, o gba ẹmi awọn eeyan lapa oku India, ẹkun-un Africa.
Ni awọn agbegbe ti oke giga ba wa wa, ilẹ maa n ya, ti yoo gbe ile rẹpẹtẹ mìn, ti iranlọwọ yoo si ṣoro lati ri fun wọn.
Ni 2015, o fẹrẹ ro eeyan ẹgbẹrun mẹsan-an to ku latari ilẹ riri nla to waye ni Nepal.
Awọn onimọ nipa ilẹ riri sọ pe ile to to ẹgbẹrun mẹta ni ilẹ to ya lagbegbe naa kan.
Ilẹ riri San Francisco to ṣẹlẹ ni 1906, mu ki ilẹ maa mi gidi fo ogun si ọgbọn iṣẹju aaya, agbara rẹ si bẹ ọpa gaasi ati ti omi niluu naa.
Gaasi to n jo gba ina lọpọ agbegbe, ai ri omi lo si jẹ ko sọro fun wọn lati pa ina naa. Bẹẹ lo si ṣe ti eeyan ẹgbẹrun mẹta di oloogbe.