Mó ní òṣìṣẹ́ 42 àmọ́ mò jẹ wọ́n lówó oṣù mẹrin, mò ń la nǹkan kọjá torí ìlú le - Ibrahim Chatta

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nnkan o fararọ lorilẹede Naijiria lọwọ yii, ẹni to ba ke lo bọmọ jẹ, bayii ni gbajugbaja oṣerẹ tiata, Ibrahim Chatta, ṣe ke gbajare nipa nnkan to n la kọja gẹgẹ oṣere lasiko yii.

Chatta sọrọ ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ pe loootọ ni eeyan mejilelogoji n ṣiṣẹ foun, amọ, oun n jẹ wọn lowo oṣu mẹrin bayii tori ilu le.

Ilumọọka oṣere naa ni, bi ọrọ-aje Naijiria ṣe dẹnu kọlẹ naa lo fa a, ti oun ko fi ri owo oṣu awọn oṣiṣẹ oun san.

Ibrahim Chatta ni awọn alaṣẹ ti wọn di ipo aṣiwaju mu ni Naijiria ni wọn ni lati ṣe daadaa fawọn araalu, ki ara le rọ gbogbo eeyan.

Chatta ni oun si duro lori ẹsẹ oun wi pe orilẹede to dara ni Naijiria jẹ, amọ, o ni awọn eeyan to wa ninu rẹ ni ko sunwọn.

Ilumọọka oṣere naa sọ pe asiko ti to fun ijọba orilẹede Naijiria lati lo awọn nnkan alumọni ti Eledua fi jinki Naijiria ki araalu naa le gbe igbe aye irọrun.

''Mi o sọrọ yii kawọn eeyan le ba mi san owo oṣu ti mo n jẹ awọn oṣiṣẹ mi''

Ibrahim Chatta ni ''Mo mọ wi pe awọn eeyan kan le fẹẹ maa bu mi, mi o sọrọ yii kawọn eeyan le ba mi san owo oṣu ti mo n jẹ awọn oṣiṣẹ mi.

Mo n sọ eleyii lati jẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ilu o fararọ ni.

Ọfẹ ni mo maa n ṣe ọpọ iṣẹ ti mo n ṣe papaa julọ fawọn ọrẹ mi lagbo oṣere.

Awọn iṣẹ mii dẹ wa to jẹ wi pe owo diẹ ni mo maa n gba lọwọ awọn akẹgbẹ mi,'' Chatta lo sọ bẹẹ.

Gbajumọ oṣere naa sọ pe awọn to n ṣakoso Naijiria ko gbagbọ ninu iwe mimọ Bibeli ati Koran.

O ni ti wọn ba gbagbọ ninu awọn iwe mimọ mejeeji yii ni, wọn o ni maa huwa bi wọn ṣe n huwa bayii.

Chatta ni ko sẹni to ran oun lati ṣe fidio ti oun ṣe yii, o ni fidio naa ko si ni ọwọ oṣelu kankan ninu.

''Mi o ni ẹnikankan lọkan pẹlu ọrọ ti mo n sọ yii, ohun ti mo fẹ kawọn eeyan mọ ni pe owo ko le ra iku.

Gbogbo nnkan ti a si n kojọ yii, ko si eleyii ti a maa ko wọ saare nibẹ."

"Ko si ẹni to janfaani owo ti Aarẹ Goodluck Jonathan ya sọtọ fawọn oṣere lasiko ijọba rẹ, ẹ bẹru Ọlọrun"

Agba osere naa tun fi kun pe "Ko si iyatọ laarin gbogbo awọn oloṣelu Naijiria, ọkan naa ni gbogbo wọn ẹgbẹ oṣelu kan le yatọ ni.

Lẹẹkan sii, mi o ba ẹnikankan wi o, mi o ba aarẹ wa wi.

Gbogbo awọn to wa ni ipo aṣẹ ni ọrọ yii kan, Anabi si ti sọrọ naa ṣaaju wi pe ni igbẹyin aye awọn alaṣẹ yoo daju.

Anabi tun ni awọn olowo yoo lahun debi wi pe wọn ko ni fẹ fun ẹnikẹni ninu ohun ini wọn.

Bakan naa ni Anabi tun sọ pe awọn talaka igba naa yoo ya opurọ, eyi to ti n ṣẹlẹ bayii,'' Chatta ṣalaye.

Chatta ni ko si ẹni to janfaani owo ti Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan, ya sọtọ fawọn oṣere lasiko ijọba rẹ.

O ni ati olori ati ọmọ ẹyin ni iwa wọn ko dara lorilẹede Naijiria.

Gbajumọ oṣere naa wa rọ awọn alaṣẹ ni Naijiria wi pe ki wọn bẹru Ọlọrun ki wọn si ṣe daadaa fun araalu.

Chatta ni titun orilẹede Naijiria ṣe kan gbogbo eeyan, ati olori atawọn araalu.