Asamoah Gyan, òdú agbábọ́ọ̀lù Ghana fẹ̀yìntì

Asamoah Gyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbajumọ agbabọọlu ọmọ orilẹede Ghana, Asamoah Gyan ti kede ifẹyinti rẹ kuro ninu ere bọọlu agbajẹun.

Gyang kede loju opo Twitter rẹ pe “asiko to lati fi aṣọ ati bata ere ije mi kọ pẹlu ogo bi mo ṣe n fẹyinti kuro ni bọọlu agbajẹun.”

Goolu mọkanlelogun ni Asamoah Gyan gba wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọfa to gba fun ikọ Black Stars orilẹede Ghana.

Lọwọ yii, oun ni agbabọọlu to gba goolu wọle si awọn julọ fun orilẹede Ghana.

Ki lo yẹ kẹẹ mọ nipa Asamoah Gyan?

Sunderland lo dari si ni liigi orilẹede United Arab Emirates nibi to ti gba bọọlu fun Al Ain, ki o to tun lọ si orilẹede China pẹlu ẹgbẹ agbabọlu Shanghai SIPG.

Nigba to wa ni UAE, oun ni atamatase to gba goolu sawọn julọ ni liigun orilẹede naa pẹlu goolu mejidinlọgbọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mejilelọgbọn to gba.

Asamoah Gyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa lo gba bọọlu jẹun lẹgbẹ agbabọọlu Kayserispor ati North East United.

Eekan ni Asamoah Gyan ni ikọ orilẹede Ghana, o si kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 22006, 2010 ati 2014.

Oun ni agbabọọlu Afirika to gba goolu wọle julọ ni idije ife ẹyẹ agbaye.

Ẹwẹ, idije ife ẹyẹ Afrika meje lo ti kopa fun orilẹede Ghana nibi ti wọn ti ṣe ipo kẹta ni dun 2008; ipo keji ni ọdun 2010 ati 2015.

Ẹgbẹ agbabọọlu Legon Cities FC lorilẹede Ghana ni Gyan ti gba bọọlu jẹun kẹyin ki o to wa fi adagba rọ.