You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko tún ṣàwárí abẹ́ afárá ni Osborne ní Island tí àwọn èèyàn n gbé
Lojuna lati fọ ilu Eko mọ, ati lati dẹkun iwa ibajẹ, ijọba ipinlẹ Eko ti jẹ ko di mimọ pe awọn tun ti ṣawari abẹ afara ti awọn kan tun sọ di ile, lati maa gbe.
Kọmiṣọ́nna fọrọ eto ayika ati omi, Ọnarebu Tokunbọ Wahab lo sọ eyi di mimọ loju opo ayelujara ti X rẹ l’Ọjọbọ to kọja.
Tokunbọ Wahab ni abẹ afara Osborne to wa ni Ikoyi lawọn ti ṣawari ibi ti awọn eeyan naa sọ di ile wọn lati maa gbe.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Wahab sọ pe awọn ṣawari yara mẹrindinlaadọrun-un ti awọn kan ṣe si abẹ afara Dolphin Estate, nibi ti wọn ti n gba ẹgbẹrun lọna igba ati aabọ (N250,000) naira lọdọọdun.
O ni awọn iwa wọnyi ko ba oju mu to, to si n tabuku ba ipinlẹ naa.
Wahab wa fi kun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ to n ṣabojuto imọtoto ayika ati agbegbe, Lagos State Environmental Sanitation Corps ti a mọ si KAI ni wọn lọ ko gbogbo awọn to n sun si abẹ afara naa.
Bẹẹ lo ni wọn ti palẹmọ gbogbo ẹru wọn kuro loju ẹsẹ.
Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ ni ana?
Ṣé lóòótọ́ ni pé ìjọba Eko ṣàwárí yàrá 86 táwọn èèyàn tí ń san N250,000 lábẹ́ afárá?
Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ti ṣawari awọn yara ti ko din ni ẹgbẹrun mẹrindinlaadọrun-un (86) labẹ afara Dolphin Estate to wa ni Ikoyi, ipinlẹ naa, nibi ti awọn eeyan ti n san obitibiti owo lati sun si.
Ẹgbẹrun lọna ọtalenigba (N250,000) naira ni a gbọ pe awọn olugbe yara to wa ni abẹ afara yii n san lọdọọdun.
Kọmiṣanna fọrọ eto ayika ati omi, Ọnarebu Tokunbọ Wahab lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọru, ọsẹ yii.
O ni niṣe ni awọn kan da afara naa si wẹwẹ pẹlu ṣọọbu onirin ti wọn tun gbe sibẹ lati maa fi gba owo lọwọ awọn eeyan, ki wọn le maa fori pamọ sibẹ.
Tokunbọ Wahab sọ pe eyi ko ba oju mu rara, to si ni ijọba ti lọ le gbogbo wọn danu, ati pe wọn ti tu awọn yara ọhun ka.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn mejidinlogun ni ọwọ awọn tẹ lasiko ti awọn lọ sibẹ.
Bakan naa, oludamọran pataki fun Gomina Babajide Sanwo-Olu, Ọgbẹni Kunle Rotimi-Akodu nigba toun naa n ṣafikun lori iṣẹlẹ yii jẹ ko di mimọ pe ọjọ Iṣẹgun to kọja ni awọn ileeṣẹ eleto aabo ayika ti a mọ si Lagos State Environmental Sanitation Corps, ti a mọ si KAI lọ le wọn danu.