You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bàbá àtọmọ tó kó sọ́wọ́ ajínigbé l’Ondo gba ìtúsílẹ̀
Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti amọ si Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn ti ri baba ati ọmọ rẹ ti awọn ajinigbe jigbe lọjọ Aje, ọsẹ yii gba jade.
Ọga agba ileeṣẹ naa, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ lo sọ eyi di mimọ lasiko to n fi to awọn akọroyin leti niluu Akurẹ lọjọ Iṣẹgun to kọja.
Bi ẹ ko ba gbagbe, baba naa, Ọgbẹni Malik Onose ati ọmọ rẹ, Jethro Onose ni awọn ajinigbe jigbe lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2024 lopopona marosẹ ilu Eko si Ondo.
Asiko ti wọn ni baba naa n mu ọmọ rẹ pada lọ sile-ẹkọ rẹ, iyẹn ile-ẹkọ awọn ọmọ ogun ori omi orileede Naijiria, eyi to wa niluu Imeri, ijọba ibilẹ Ose, ipinlẹ Ondo ni wọn lawọn agbebọn ọhun da wọn lọna, ti wọn si ko wọn wọnu igbo lọ.
Gẹgẹ bi Adelẹyẹ ṣe ṣalaye, o ni ko ju bii kilomita mẹta lati wọ ipinlẹ Ondo ni iṣẹlẹ ọhun ti waye lagbegbe ipinlẹ Ẹdo.
Ninu ọrọ rẹ to fi lede, o ni “Nigba ti a gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe yii, ileeṣẹ Amotekun kan si ajọ ọmọgun ori omi loju ẹsẹ, eyi lo si ṣokunfa bi ajọsọ ṣe wa lati doola ẹmi awọn mejeeji yii kuro lahamọ awọn oniṣẹ ibi.
“Gbogbo inu igbo ni agbegbe iṣẹlẹ ọhun la wọ, ṣugbọn ti awọn pada ri iṣẹ naa ṣe laṣepe nipa gbigba wọn silẹ. Ni bayii, awọn mejeji ti darapọ mọ ẹbi wọn layọ ati alaafia.”
Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ seyin?
Bàbá àtọmọ kó sọ́wọ́ ajínigbé ní Ondo, ọlọ́pàá ati iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Àwọn agbebọn tẹni kẹni ko mo ẹyẹ to ṣu won ti ji akẹkọọ kan, Jethro Onose ati baba rẹ, Malik Onose gbe.
Lasiko ti wọn n rinrin àjo lati ipinlẹ Edo lọ si ilu Imeri ni ijọba ibilẹ Ose, nipinlẹ Ondo ni wọn ko sọwọ awọn ajinigbe naa.
Owurọ ọjọ Aje ni awọn mejeeji yii ko sọwọ awọn ajinigbe naa ti wọn si mu wọn wọ igbo lọ.
Akẹkọọ ile ẹkọ girama ajọ ọmọ ogun ori omi orilẹ ede Naijiria ni Jethro ẹni ti baba rẹ, Malik n mu lọ si ile ẹkọ to wa ni Imeri lẹyin ti isinmi ọsẹ mẹta awọn ti akẹkọọ pari.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya fidi iṣẹlẹ naa múlẹ.
O sọ pe akitiyan ti bẹrẹ lati gba itusilẹ baba ati ọmọ ti awọn agbebọn jigbe naa.
Odunlami-Omosanya ni awọn Ikọ ọlọpaa pẹlu ajọṣepọ ajọ ọmọ ogun ori omi ti bẹrẹ igbesẹ lati doola ẹmi baba ati ọmọ to wa ni igbèkun awọn ajinigbe ọhun.