Wo ààrẹ orílẹ́èdè mẹ́sàn-án tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú

Iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu agberapa ti a mọ si Helicopter ti gba ẹmi Aarẹ Ebrahim Raisi ti orileede Iran.

Ohun to ṣẹlẹ ti wa jẹ ki oju awọn eeyan la si awọn eekan-eekan kaakiri orileede to wa ni agbaye, ti awọn naa ti ba iru ijamba bayii lọ.

Awọn iṣẹlẹ bayii lo si jẹ pe o maa ni ipalara fun eto ipo oṣelu, awujọ, paapaa eto ọrọ aje.

Ni bayii, a ti mu awọn aarẹ orileede kaakiri agbaye ti awọn naa ti ba iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu di ẹni ana.

Aarẹ Ebrahim Raisi ti orileede Iran

Ni irọle ọjọ Aiku to kọja yii, ọkọ baalu agberapa to n gbe Aarẹ ilẹ Iran, Aarẹ Ebrahim Raisi; to fi mọ awọn bii minisita fọrọ ilẹ okeere, Hossein Amirabdollahian; Gomina East Azarbaijan, Malek Rahmati; ati alakoso eto adura Tabriz ti ọjọ Ẹti, Hojjatoleslam Al Hashem, ni wọn ba ijamba ọhun lọ.

Ko si ẹnikankan to ye ninu gbogbo awọn to wa ninu ọkọ baluu yii.

Aarẹ José Félix Estigarribia orileede Paraguay

Ọjọ keje, oṣu kẹsan, ọdun 1940 ni aarẹ kẹtalelọgbọn lorileede Paraguay padanu ẹmi rẹ sinu ijamba ọkọ ofurufu ti Potez 25.

Ilu ti wọn n pe ni Altos, lorileede Paraguay ni ijamba ọhun ti waye lọdun naa lọhun.

Aarẹ Ramon Magsaysay orileede Philippines

‘Ko le jẹ bẹẹ, irọ ni’ lohun to n jade lẹnu ara eeyan orileede Philippines nigba ti iroyin ọhun jade sita pe aarẹ wọn ti jade laye.

Ọjọ manigbagbe si ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, ọdun 1957 jẹ ninu itan orileede naa titi di asiko yii.

Aarẹ keje ni Magsaysay jẹ fun orileede naa. Inu ọkọ baluu ti nọmba rẹ C-47 lo ti padanu ẹmi rẹ.

Ori oke Mount Manunggal lo jabọ le, ti a si gbọ pe ẹnikan ṣoṣo ni ori ko yọ ninu awọn marundinlọgbọn ti wọn wa ninu rẹ.

Aarẹ Abdul Salam Arif ti orileede Iraq

Aarẹ keji ni Aarẹ Abdul Salam Arif jẹ lorileede Iraq, ko si sẹni to lero wi pe yoo tete ku, nitori ti wọn sọ pe ko ṣaisan.

Ọkọ baluu rẹ ti de Havilland DH.104 Dove la gbọ pe o deedee ja lulẹ lọjọ kẹtala, oṣu kẹrin, ọdun 1966 nitosi ibi kan ti wọn pe ni Basra.

Iku rẹ lo si mu ki awọn alakoso Iraq nigba naa yan aburo rẹ Abdul Rahman Arif lati tẹsiwaju.

Aarẹ René Barrientos Ortuño ti orileede Bolivia

Irọ to pada di otitọ ni ti iroyin iku Aarẹ orileede Bolivia, René Barrientos Ortuño.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 1969 ni ọjọ manigbagbe ti aarẹ kẹtadinlaadọta naa jade laye.

Bo tilẹ jẹ pe ohun ti awọn eeyan n sọ nigba naa ni pe niṣe ni wọn ṣeku pa René Barrientos Ortuño, ṣugbọn ti wọn ko ri idi rẹ lati fi mulẹ.

Aarẹ Samora Moisés Machel ti orileede Mozambique

Aarẹ akọkọ lorilede Mozambique ni Samora Moisés Machel jẹ. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 1986 loun naa padanu ẹmi rẹ sinu ijamba ọkọ ofurufu nitosi ẹnu ibode South Africa.

Aarẹ Muhammad Zia-ul-Haq ti orileede Pakistan

Ipo kẹfa ni Muhammad Zia-ul-Haq wa ninu awọn aarẹ to jẹ nilẹ Pakistan.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 1988 loun padanu ẹmi rẹ sinu ijamba ọkọ ofurufu C-130 Hercules.

Ko pẹ ti wọn lo gbera niluu Bahawalpur ni wọn sọ pe o ja lulẹ lojiji.

Titi di asiko yii ni ko sẹni to le fidi rẹ mulẹ nipa ohun to fa ijamba naa, bo tilẹ jẹ pe ohun ti wọn n sọ pe ni ẹnjiini rẹ lo da iṣẹ silẹ lori iṣẹ.

Aarẹ Juvénal Habyarimana ti orileede Rwanda ati Aarẹ Cyprien Ntaryamira ti Burundi

Orileede meji ọtọọtọ lo ṣofo lọjọ kan ṣoṣo nigba ti awọn aarẹ wọn padanu ẹmi wọn lairo tẹlẹ.

Lọjọ kẹfa, oṣu kẹrin, ọdun 1994 ni awọn aarẹ naa, Aarẹ Juvénal Habyarimana ti orileede Rwanda ati Aarẹ Cyprien Ntaryamira ti Burundi jade laye.

Ọkọ baluu wọn ti Dassault Falcon 50 ni wọn lo da iṣẹ silẹ nitosi Kigali to wa ni Rwanda.

Aarẹ Lech Kaczyński ti orileede Poland

Ko sẹni to le gbagbe Aarẹ Lech Kaczyński ti orileede Poland to ku lọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, ọdun 2010.

Inu ijamba ọkọ baluu loun naa padanu ẹmi rẹ si nitosi agbegbe ti wọn pe ni Smolensk, lorileede Russia.

Gbogbo awọn mẹrindinlọgọrun to wa nibẹ lo ku.