You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòtọ́ọ́ ni adẹ́rìn-ínpòṣónú Mr Macaroni ń múra ìgbéyàwó?
Lara ohun tawọn eeyan n sọ nipa rẹ julọ lori ayelujara ni awọn fọto ti adẹrin-inpoṣonu, Debo Adedayo ti ọpọ mọ si Mr Macaroni fi ṣoju opo Instagram ati Facebook rẹ lọjọ Aje ogunjọ oṣu Karun un ọdun 2024 yii.
Mr Macaroni fi fọto to ṣafihan bi o ṣe di mọ arẹwa obinrin kan pẹki peki pẹlu ẹri lẹnu awọn mejeeji ṣoju opo ayelujara rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Mr Macaroni ko kọ nkan nkan sori awọn fọto naa, ọpọ lo ti n sọ pe afaimọ ko maa jẹ pe Ọgbẹni Adedayo ti n mura igbeyawo.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Mr Macaroni yoo fi iru fọto yii lede loju opo ayelujara rẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, Mr Macaroni fi fọto ara rẹ ati ọmọbinrin ti wọn n jọ ṣiṣẹ pọ, Kemi Ikuseedun ti ọpọ mọ si Mummy Wa ninu ere ṣoju opo ayelujara rẹ lọdun 2022.
Koda, ọpọ ninu fọto ọhun ni ṣe pẹlu fọto tawọn to n mura igbeyawo maa n ya.
Awọn miran ninu awọn fọto naa jẹ fọto ti Mr Macaroni ati Mummy Wa ti wọn aṣọ igbeyawo.
Eyi gan an lo jẹ ki ọpọ eeyan ro pe igbeyawo fẹ waye laarin wọn.
Amọ, Mr Macaroni pada ṣalaye pe ko si ohun to jọ pe oun fẹ ṣe igbeyawo pẹlu Mummy Wa.
Lẹyin to dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ tan ni o ṣalaye pe oun ko tii ṣe igbeyawo o.